Awọn Oloro marun-un dero atimọle n’Idiroko, awọn Musulumi to n kirun ni wọn kọ lu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ yii, lawọn kan ti wọn n ṣe ọdun Oro, sede lojumọmọ n’Idiroko, lagbegbe Temitọpẹ, ti wọn ko jẹ kawọn to fẹẹ lọ soko iṣẹ wọn atawọn to fẹẹ lọọ jọsin rin bo ṣe wu wọn. Ohun to sọ marun-un ninu wọn dero ẹyin gbaga niyẹn.

Nigba to n sọrọ nipa bawọn Oloro naa ṣe dero atimọle, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe niṣe ni awọn Oloro yii kọ lu mọṣalaaṣi kan, ti wọn si tun ṣe aafaa ibẹ leṣe. O ni ọpọlọpọ igba lawọn ọlọpaa ti kilọ fun wọn pe o lodi sofin lati maa sede lọsan-an, ti wọn ko ni i jẹ kawọn to fẹẹ lọọ jọsin nilana mi-in rin, ti awọn Oloro yii yoo si maa jaye alabata ni tiwọn niluu to lofin.

O tẹsiwaju pe ọga awọn ti i ṣe kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun tun lọọ ba wọn sọrọ lori isede yii, wọn ko gbọ, bẹẹ ni ọpọlọpọ igba nileeṣẹ ọlọpaa Ogun ti kilọ fun wọn pe ki wọn yee ṣe bẹẹ, to jẹ tinu wọn ni wọn n ṣe.

Oyeyẹmi sọ pe bi wọn ṣe kọ lu mọṣalaaṣi ti wọn tun ṣe aafaa leṣe lo jẹ kawọn mu wọn.

O lawọn taari wọn si kootu fun ijẹjọ, adajọ faaye beeli silẹ fun wọn, ṣugbọn wọn ko ri eto naa ṣe, ohun to jẹ ki marun-un ninu awọn Oloro naa tọwọ ba wa latimọle niyẹn, wọn yoo si wa nibẹ titi digba ti wọn ba too ri eto beeli wọn ṣe ni.

Awọn tiṣẹlẹ yii  ṣoju wọn sọ pe Bọla Wasiu ni aafaa ti wọn kọ lu naa n jẹ. Wọn ni ada ni wọn fi ṣa a lori nitori o jade lasiko ti wọn n ṣe ọdun oro, bẹẹ mọṣalaaṣi lọkunrin naa n lọ.

Wọn ni ọjọ Satide ọsẹ to kọja lawọn oloro naa ti kọkọ kede pe ẹnikẹni ko gbọdọ jade, ni imurasilẹ fun ọdun oro naa, wọn si sede.

Nigba tawọn aafaa si jade lọjọ Iṣẹgun, ti wọn tiẹ ti n kirun ninu mọṣalaaṣi lọwọ ni awọn Oloro naa debẹ ti wọn doju ija kọ wọn, titi kan awọn obinrin gan-an.

Nigba ti ikọlu naa pọ la gbọ pe awọn ara mọṣalaaṣi koju wọn ti wọn si ri mu ninu awọn oloro naa, ti wọn fa wọn fọlọpaa.

Iru iṣẹlẹ yii ti waye lagbegbe kan yii kan naa ri loṣu kẹjọ, ọdun 2019, lasiko ti wọn n ṣọdun Oro bii eyi naa ni, to di pe awọn oloro kọ lu wọn, ti wọn si fọ awọn ferese to wa ninu mọṣalaaṣi naa.

Ṣugbọn lasiko yii tọwọ ti ba ninu wọn, awọn ọlọpaa ti ni wọn yoo jiya iwakiwa ti wọn hu naa.

 

Leave a Reply