Awọn oloye Ibadan ti tun ni ki lọọya gbe iwe ẹjọ kuro ni kootu, wọn lawọn o ṣẹjọ mọ

Jọkẹ Amọri

Awọn oloye Olubadan ilẹ Ibadan ti gomina Ajimọbi fun lade ti paṣẹ pe ki agbẹjọro wọn, Kunle Ṣọbalaje, fagi le ejọ tawọn pe ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni kootu. Eyi ṣẹlẹ lẹyin ti awọn eeyan yii ti kọkọ gbe iwe ẹjọ mi-in kalẹ ni kootu, leyii to yatọ si adehun to wa laarin wọn pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde nibi ipade ti wọn ṣe ni bii ọjọ diẹ sẹyin.

Ninu iwe kan ti  wọn fun awọn oniroyin, ALAROYE gbọ pe awọn eeyan naa ti kọwe si agbẹjọro wọn, Kunle Ṣọbalaje, lọgbọnjọ, oṣu kin-in-ni, yii, pe ko gbe ẹjọ ti awọn pe ipinlẹ Ọyọ lati ta ko bi wọn ṣe lodi si ade ti Isiaka Ajimọbi fun wọn kuro ni kootu. Wọn ni igbesẹ naa waye lati ma ṣe gbegi dina alaafia to ti n jọba niluu Ibadan.

Ninu lẹta naa ni wọn ti sọ pe ṣiṣe atunṣe si oye Ibadan gẹgẹ bi ofin ọdun 1957 ṣe la a kalẹ gbọdọ duro bayii na titi ti Olubadan tuntun yoo fi gbọpa aṣẹ.

A gbọ pe mẹfa ninu awọn oloye mẹjọ to gbọpa aṣẹ naa lo fọwọ si iwe lati gbe ẹjọ naa kuro ni kootu, nigba ti awọn meji ko ṣe bẹẹ.

Laipẹ yii ni Lọọya Micheal Lana to n ṣoju fun Olubadan ati Ṣẹnetọ Ladọja sọ pe awọn eeyan naa ko fẹẹ ṣiika adehun ti awọn jọ ṣe. Wọn ni dipo ki wọn gbe ẹjọ naa kuro ni kootu gẹgẹ bi awọn ṣe jọ fẹnuko si nigba ti wọn ṣepade pẹlu gomina, niṣe ni wọn tun gbe iwe ẹjọ mi-in dide, ti wọn si sọ pe awọn fẹẹ tẹsiwaju ninu ẹjọ naa.

Ṣugbọn ni bayii ti wọn ti tun jade pe awọn ti pa lọọya awọn laṣẹ lati gbe ẹjọ naa kuro ni kootu, o ṣee ṣe ki ọrọ naa lojutuu.

Ohun ti awọn to n woye bọrọ naa ṣe n lọ n sọ ni pe ọrọ awọn oloye ibadan yii ko jọ pe yoo tan bọrọ. Wọn ni ko ma jẹ pe ọgbọn ti wọn n da ni lati ri i pe Olubadan tuntun toun naa wa ninu awọn oloye Ibadan to gbade, Oloye Lekan Balogun, bọ sipo. Wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ pe nigba ti ọkunrin naa ba bọ sipo tan, o le lo agbara rẹ gẹgẹ bii Olubadan lati ṣatunṣe si ofin oye jijẹ niluu Ibadan.

Tẹ o ba gbagbe, ni ọsẹ meji sẹyin lawọn oloye Ibadan yii ṣepade pọ pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde, ti wọn si gba pe ki wọn lọọ gbe ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ naa kuro, ki igbesẹ lati fi Olubadan jẹ si bẹrẹ kiakia.

Lẹyin ipade naa ni Agba-Oye ilẹ Ibadan, Rashidi Adewọlu Ladọja, ba awọn oniroyin sọrọ, nibi to ti sọ pe Lekan Balogun ni ipo Olubadan tọ si, ohun naa ni yoo si wa ni ipo naa. Bẹẹ lo fi da awọn eeyan loju pe ko si wahala kankan laarin awọn lori ipo Oubadan.

Leave a Reply