Awọn olukọ tijọba le danu fẹhonu han ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Awọn olukọ to le ni ẹgbẹrun meji tijọba ana gba sẹnu iṣẹ lọdun 2019, ṣugbọn tijọba to wa lori ipo bayii le laipẹ yii tu jade l’Ọjọruu, Wẹsidee, nipinlẹ Kwara lati fẹhonu han ta ko bijọba ṣe gbaṣẹ lọwọ wọn.

ALAROYE ṣakiyesi pe lọsan-an gangan lawọn olukọ naa gba gbogbo iwaju abawọle ile ijọba lati fẹhonu han.

Wọn wa nibẹ titi asiko irun aago meji, koda, iwaju ile ijọba ti wọn wa gan-an ni wọn to si lati kirun.

Niṣe ni wọn n sọrọ pẹlu omije loju pe kijọba ṣaanu awọn.

Ṣe lọsẹ to kọja ni ijọba kede pe ki gbogbo awọn olukọ naa gba ile wọn lọ nitori pe ilana ti wọn fi gba wọn sẹnu iṣẹ lọwọ jibiti ninu.

Ijọba loun yoo ṣi ikanni igbanisiṣẹ mi-in lọdun 2021, lati gba awọn olukọ nibaamu pẹlu ofin ati ilana igbanisiṣẹ, ṣugbọn o fun awọn to jawee gbele-ẹ fun lanfaani lati tun kopa ninu eto igbanisiṣẹ.

Lara ẹsun tijọba Abdulrahman Abdulrazaq fi kan ijọba to lọ ni pe asiko ti eto idibo sun mọ etile ni wọn rọ awọn eeyan ọhun sẹnu iṣẹ lati le ri ojurere wọn ati pe ọpọlọpọ awọn ti wọn rọ sibẹ ni wọn ko kunju oṣuwọn rara, ẹlomin ko ni iwe-ẹri nileewe olukọ.

Kete tijọba to wa nipo yii bọ sori aleefa lo da sisan owo-oṣu awọn olukọ tuntun naa duro, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ariwo, ijọba yi ipinnu rẹ pada, to si san gbogbo owo-oṣu to jẹ wọn lọsẹ to kọja yii.

Leave a Reply