Awọn oluranlọwọ igbakeji gomina Kwara ti ko arun Korona

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Lẹyin ọjọ diẹ ti arun Korona pa olori oṣiṣẹ gomina nipinlẹ Kwara, Aminu Adisa Logun, awọn oluranlọwọ Igbakeji gomina, Kayọde Alabi, ti lugbadi arun naa.

Eyi waye pẹlu bi eeyan mọkanlelaaadọrin ṣe kun iye awọn to ti ko arun naa nipinlẹ Kwara.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin igbakeji gomina, Modupẹ Joel, gbe sita lọjọ Aiku, Sannde, ana, lo ti ni Ọgbẹni Alabi ke si araalu lati maa tẹle gbogbo ilana tawọn ẹleto ilera la kalẹ.

O ni arun Korona daju, o si lewu pup, idi niyi to fi yẹ kawọn eeyan maa kiyesara. O fi kun un pe ijọba ti n sa gbogbo ipa lati dẹkun atankalẹ arun naa nipinlẹ Kwara.

Alabi ni awọn oluranlọwọ oun to lugbadi arun ọhun ti wa nibudo ti wọn ti n tọju arun nilewosan akọṣẹmọṣẹ Sobi, niluu Ilọrin.

Ṣaaju lo ti lọọ ṣe ayẹwo ara rẹ, ti esi-ayẹwo naa si fi han pe ṣaka lara rẹ da.

O gba awọn alaṣẹ ijọba nimọran lati tẹle apẹrẹ oun, ki wọn si lọ ṣe ayẹwo ara wọn ni kiakia.

Leave a Reply