Awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan ṣewọde ta ko ki Musulumi jẹ aarẹ ati igbakeji

Monisọla Saka

Ọgọọrọ awọn eekan ati alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn fọn sori titi nipinlẹ Eko lati fẹhonu han lori ipinnu ti ẹgbẹ wọn ṣe lati fa ẹlẹsin kan naa kalẹ fawọn ipo meji to ga ju nilẹ Naijiria ninu ibo to n bọ lọna.

Awọn olufẹhonu-han yii ti wọn jẹ agbarijọpọ APC Stakeholders Network ati Southwest Supporters of Tinubu bẹrẹ iwọde wọọrọwọ wọn lati ile itaja igbalode Shoprite, to wa n’Ikẹja, gba ti ile ijọba ipinlẹ Eko, ni Alausa.

Lasiko ti wọn n kọrin iṣọkan naa, awọn eeyan yii gbe oriṣiiriṣii patako ti wọn kọ awọn ẹdun ọkan wọn si lọwọ, ninu sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ ti iwọde wọn da silẹ loju ọna ọhun. Lara awọn nnkan ti wọn kọ sinu patako ti wọn gbe dani ni, ‘Baba Aṣiwaju wa ọwọn, nitori awọn ọmọ Yoruba, ẹ fi ẹlomi-in rọpo Shettima,’ Ẹ fi Kirisitẹni rọpo Shettima’,  Tinubu ati Buhari, ẹ tun ero yin pa lori Musulumi meji to fẹẹ dupo Aarẹ’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Boya ni iwọde tawọn kan ṣe lọ sile ẹgbẹ APC l’Abuja le ti i pe ọsẹ kan ti wọn fi fẹhonu han l’Ekoo yii naa. Lasiko ti Tinubu fẹẹ ṣafihan Shettima to jẹ gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, to si tun jẹ Musulumi bii tiẹ gẹgẹ bii igbakeji ẹ ni gbọngan nla Shehu Musa Yar’Adua, l’Abuja, lawọn oluṣewọde naa ya lọ si Abuja.

Iwọde ọhun tawọn ọdọ Hausa-Fulani inu ẹgbẹ oṣelu APC ṣe ni wọn ti fi ẹdun ọkan wọn han si awọn olori ẹgbẹ wọn.

Nigba ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ niwaju ile ijọba ipinlẹ Eko, l’Alausa, Aarẹ ẹgbẹ awọn ti wọn ṣewọde yii, Alagba Samuel Arokoyọ,  ṣalaye pe idiwọ kan ṣoṣo to wa fun Aṣiwaju Bọla Tinubu lori atiwọle rẹ fun ibo aarẹ ọdun 2023 ni ẹni to yan gẹgẹ bii igbakeji ẹ, iyẹn Sẹnetọ Kashim Shettima.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, pupọ ninu awọn alatilẹyin ẹ, titi kan awọn eeyan apa iha Guusu Ariwa ilẹ yii, ti wọn tun jẹ Yoruba bii tiẹ, ni ọrọ Musulumi bii tiẹ to mu fun igbakeji aarẹ n dun.

Arokoyọ ni ọna kan ṣoṣo ti Tinubu, gẹgẹ bii aṣaaju rere ati eekan ninu oloṣelu ilẹ yii, to si ti kopa ribiribi ninu ẹgbẹ oṣelu le fi ra iyi funra ẹ pada ni lati fi ẹlẹsin Kirisitẹni rọpo Shettima.

O ni, “Tinubu ti ṣe gudugudu meje, yaaya mẹfa, ninu oṣelu awa-ara-wa lorilẹ-ede yii gẹgẹ bii eekan to jẹ fun bii ogoji ọdun, fun idi eyi, igba ọtun la ri ijawe olubori ẹ gẹgẹ bii ọmọ oye fun ipo aarẹ lẹgbẹ APC jẹ.

“Ti bata ẹsin kan ba ti n ro pọnla pọnla ju, to si fẹẹ maa jẹ gaba le awọn to ku lori, o le tubọ fa iyapa, ko si ba ẹmi ifẹ tawọn eeyan ti fi n bara wọn lo lati ọjọ to ti pẹ, paapaa ju lọ, nilẹ Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede to kun fun oniruuru ẹsin ati ẹya jẹ.

Idi si niyi to fi jẹ pe Shettima ti Aṣiwaju mu yii jẹ okunfa iyapa laarin awọn eeyan ilẹ yii”.

Awọn ẹgbẹ yii waa fi kun un pe pataki iwọde wọọrọwọ tawọn ṣe ni lati rọ oludije dupo aarẹ lẹgbẹ wọn lati ju Shettima silẹ, ko si mu ẹlomi-in, ko ma baa si ikunsinu, ko si le tun ara ẹ ṣe lọtun-un ati losi.

Arokoyọ ni, ti Tinubu ba le mu ọmọlẹyin Kirisiti lati apa Ariwa, idaniloju wa pe o le ri ida aadọrin ibo lati awọn ipinlẹ apa Ariwa bii Kogi, Kwara, Plateau, Nassarawa, Benue, Taraba, Kaduna, Adamawa, Gombe, Borno, ati olu ilu orilẹ-ede yii ti ibo wọn yoo si fi iyatọ han.

Arokoyọ tun tẹsiwaju ni ‘‘Iha Aarin Gbungbun Ariwa orilẹ-ede yii tawọn ọmọlẹyin Kirisiti pọ si ko ipa pataki ninu ibo aarẹ ọdun 2015 ati 2019. Bi Aarẹ Buhari si ṣe gbajumọ to lapa Ariwa, igba kan ṣoṣo to rọwọ mu naa ni igba to gbegba oroke laduugbo rẹ pẹlu bo ṣe jẹ pe oun lo maa n rọwọ mu ju lapa Iwọ Oorun ati Ila Oorun Ariwa tawọn Musulumi pọ si lẹẹmẹta akọkọ to kọkọ gbegba ibo aarẹ.

“Ti Tinubu ba le gbe igbesẹ yii, yoo dẹni iyi, ẹni ẹyẹ ti wọn o ni i gbagbe ninu itan, yoo si di aayo awọn ọmọlẹyin Kirisiti

Leave a Reply