Awọn ọmọ ẹgbẹ APC kọju ija sira wọn niluu Ọffa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gbọn mi si i, omi o to o, to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu APC niluu Ọffa ko ti i dopin, orogun meji ninu ẹgbẹ ọhun ṣakọlu sira wọn niluu naa, ọpọ fara pa yanna yanna, ti wọn si dero ile iwosan.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni igun to n ṣatilẹyin fun Sẹnetọ to n ṣoju Guusu ipinlẹ Kwara, Sẹnatọ Lọla Ashiru, ati igun to n ṣe atilẹyin fun Kọmisanna to n ri si ọrọ omi nipinlẹ Kwara, Họnọrebu Fẹmi Agbaje, ti wọn jọ jẹ ọmọ bibi ilu Ọffa, n rọjo ibọn lu ara wọn, eyi to mu kawọn eeyan sa asala fun ẹmi ara wọn.

Wọn gbe awọn to fara pa lọ si awọn ileewosan ọtọọtọ to wa niluu Ọffa, nigba ti wọn gbe awọn miiran lọ si ọsibitu jẹnẹra tiluu Ilọrin.

ALAROYE gbọ pe Họnọrebu Fẹmi lo maa n ṣeto lori redio ni ọsọọsẹ, ibẹ lo ti sọ pe awọn oloṣelu kan ti lo ọdun meji lori ipo, wọn o si mu gbogbo ileri ti wọn ṣe fawọn araalu ṣẹ, sugbọn wọn n reti ki oun maa gbe oriyin fun wọn, ko le jọ ọ. Bo tilẹ jẹ pe Fẹmi ko darukọ oloṣelu kankan, sugbọn nitori ikunsinu to wa laarin oun pẹlu Sẹnetọ Lọla Ashiru, wọn ni oun lọkunrin yii n ba wi.

Fẹmi Agbaje, Mallam Abdulmajeed ati awọn miiran ni wọn gbe eto kan kalẹ ti wọn n kaakiri lati wọọdu si wọọdu ilu Ọffa lati fi ṣe atilẹyin fun Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, tawọn janduku si dabaru eto ọhun, wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ (Honda) ni awọn to jẹ alatilẹyin Sẹnetọ Lọla Ashiru gbe wa sibi eto naa, ti wọn kọkọ n ju afọku igo si oju agbo, ko too di pe wọn n yinbọn, ti gbogbo ẹ si di bo o lọ o ya fun mi.

Leave a Reply