Awọn ọmọ ẹgbẹ APC tu jade lati ṣeto iforukọsilẹ ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Yatọ si ohun tawọn eeyan n ro ṣaaju akoko yii pe o ṣee ṣe ki wahala ati rogbodiyan bẹ silẹ nibi eto iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni Kwara, wọọrọwọ ni kinni ọhun bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, pẹlu bawọn ọmọ ẹgbẹ ṣe tu jade lọpọ yanturu lọ sibudo idibo wọn.

Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara leto iforukọsilẹ naa ti waye.

Lawọn ibudo to wa niluu Ilọrin, witiwiti lawọn ọmọ ẹgbẹ APC jade lati ṣeto naa, bo tilẹ jẹ pe ero ko pọ lawọn ibudo idibo perete to wa laarin igboro, wọrọọwọ lo lọ kaakiri Aarin-Gbungbun Kwara.

Ni wọọdu kin-in-ni, ibudo idibo Alapa/Onire/Odegiwa, awọn ọmọ ẹgbẹ APC ọgọrun-un kan le mẹtalelogoji lo ti forukọsilẹ laarin aarọ ti eto naa bẹrẹ si ọwọ aago mẹta ọsan.

Alaamojuto eto naa, Ọgbẹni Tunde Jimoh Idiagbọn, ṣalaye pe ko si wahala kankan latigba ti eto naa ti bẹrẹ.

Bakan naa lọrọ ri nibudo idibo kẹwaa, karun-un ati ikejila ni Isalẹ-Koko, Wọọdu Gambari, ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ lo jade lati ṣeto iforukọsilẹ naa.

Awọn to mojuto eto naa ni Wọọdu Ibagun, Mashood Latifat, Akanbi Teslimat ati Adebayọ Muhammed Qozeem, dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ to jade bi wọn ṣe gba alaafia laaye ti wọn si huwa ọmọluabi lati mu ki eto naa lọ wọọrọ.

Bakan naa lọmọ sori ni ibudo idibo kẹrin to wa ni Idigba, ni Wọọdu Adewọle, nijọba ibilẹ Ilọrin West, awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe jẹẹjẹ lati ibẹrẹ titi de opin.

Ọmọ ile-igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ, Mashood Mustapha, ṣeto iforukọsilẹ tiẹ ni ibudo rẹ, Aiyelabẹgan, ni Wọọdu Alanamu, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ilọrin.

Eto ọhun naa lọ wọọrọ lẹkun Guusu  ati Ariwa Kwara. Senatọ Umar Sadiq to n ṣoju ẹkun Kwara North ṣe iforukọsilẹ tiẹ ni ibudo idibo Osiwera, niluu Kaiama.

Leave a Reply