Awọn ọmọ ẹgbẹ APC dara pọ mọ NNPP l’Ekoo

Monisọla Saka

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni Sẹnetọ Rabiu Kwankwaso to jẹ oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu NNPP, ṣabẹwo siluu Eko, nibi ti wọn ti ṣi ile ẹgbẹ naa tuntun si agbegbe Fadeyi, ti ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC si darapọ mọ ẹgbẹ wọn.

Gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ yii ni wọn o gbọdọ foju rena oun bayii pẹlu bi ọpọ awọn alatilẹyin rẹ ṣe ya sita lasiko ti wọn n ṣi ile ẹgbẹ tuntun nipinlẹ Eko. O ni iyalẹnu lo jẹ bi awọn eeyan ṣe tu yaaya jade lati ki oun kabọ sibi ile ẹgbẹ tuntun ti awọn fẹẹ ṣi nipinlẹ Eko ọhun.

Ile ẹgbẹ ti wọn ṣẹṣẹ ṣe ifilọlẹ rẹ sagbegbe Fadeyi, nipinlẹ Eko yii, jẹ gẹgẹ bii ipalẹmọ fun ibo gbogboogbo ọdun 2023 wa lara idi ti Kwankwaso fi de sipinlẹ naa. Funra ondupo aarẹ yii lo ṣi ile ẹgbẹ tuntun naa. Niṣe lawọn eeyan ya si gbogbo titi nipinlẹ naa, ti wọn si n pariwo orukọ ọkunrin to fẹẹ jẹ aarẹ ọhun lasiko ti eto naa lọ lọwọ, eyi to ṣe akoba fun lilọ bibọ mọto loju ọna marosẹ Eko si Ikorodu.

Ohun to mu ori Kwankwaso wu ju ni bi oun ati alaga apapọ ẹgbẹ wọn ṣe gbalejo awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun ti wọn ya kuro lawọn ẹgbẹ oṣelu, paapaa ju lọ, ẹgbẹ APC ti ipinlẹ Eko.

Abdulmumin Jibrin to jẹ agbẹnusọ igbimọ eleto ipolongo ibo aarẹ fun Kwankwaso lo gba ori ẹrọ ayelujara lọ lati kede ile ẹgbẹ tuntun ti wọn ṣi ọhun. O ni, “Ero pitimu nibi ayẹyẹ ile ẹgbẹ tuntun wa ni ṣiṣi, bẹẹ la tun ki awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun lati ẹgbẹ oṣelu mi-in kaabọ saarin wa”.

Eyi lo mu ki gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ ọhun ni idaniloju pe oun maa jawe olubori ninu ibo aarẹ ọdun to n bọ.

Kwankwaso to ti figba kan jẹ minisita feto aabo nilẹ yii ri sọ pe oun maa ya awọn ọmọ Naijiria lẹnu nipa gbigbẹyẹ lọwọ awọn oludije dupo aarẹ to ku nigba toun ba di aarẹ wọn lọdun 2023.

Bakan naa lo ṣapejuwe ẹgbẹ NNPP gẹgẹ bii eyi ti idagbasoke n ba ju lọ nilẹ alawọ dudu.

 

Leave a Reply