Faith Adebọla, Eko
Kọṣẹkọṣẹ ni wọn ni iro ibọn n dun n’Ikorodu, nipinlẹ Eko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, awọn ọlọpaa ati awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ni wọn doju irin tutu kọra wọn, ọrọ ọhun si dogun gidi.
Adugbo kan ti wọn n pe ni Igbelara, niṣẹlẹ ọhun ti waye, n’Ikorodu, ni nnkan bii aago mejila aabọ ọsan. Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ ni wọn gboju agan sawọn agbofinro laduugbo ọhun.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn kan ni wọn tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago pe awọn ọmọ ẹlẹgbẹkẹgbẹ yii tun ti gbode, wọn tun ti n wa ara wọn kiri igboro, wọn fẹẹ tajẹ silẹ.
Bii ọgan tawọn ọlọpaa ti gba ipe yii ni wọn ti dari ikọ awọn agbofinro lọ sibẹ, ṣugbọn, gẹgẹ bi Alakoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe ṣalaye f’ALAROYE ninu atẹjade to fi ṣọwọ lori atẹ ayelujara Wasaapu ẹ, o ni bi wọn ṣe foju kan awọn ọlọpaa naa ni wọn dana ibọn bolẹ, ibọn si lawọn ọlọpaa naa fi fesi pada, ni iro ibọn ba gba adugbo kan, bẹẹ ni jinnijinni bo awọn araadugbo naa.
Adejọbi ni ọpọ lara awọn ẹlẹgbẹ okunkun naa ni wọn fara gbọgbẹ, tọgbẹ-tọgbẹ naa si ni wọn sa lọ.
Ṣugbọn ọwọ tẹ meji lara wọn, Waliyu ati Timilẹyin Ọmọbọlaji, bo tilẹ jẹ pe wọn ti fara gbọgbẹ gidi, wọn si ti n gba itọju lọsibitu ti wọn ko wọn lọ.
Wọn tun ri ibọn oyinbo meji, katiriiji ibọn ti wọn ti yin mẹwaa, eyi ti wọn o ti i yin mẹfa, ada ati aake pẹlu awọn oogun oloro ti wọn o ribi ko sa lọ.
Awọn ọlọpaa ọtẹlẹyẹmu wa ni agbegbe naa lati fimu finlẹ awọn to sa lọ yii, atawọn ẹlẹgbẹ wọn to ku tọwọ ofin ko ti i to, gẹgẹ bi kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ. Wọn lawọn ẹka ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, ni Yaba, ti n ṣiṣẹ lori ọrọ yii..