Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aye’ to n daamu wọn n’Ijẹbu-Ode bọ sọwọ fijilante

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ọjọruu, ọgbọnjọ, oṣu kejila yii, ki i ṣe ọjọ ire fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye mẹta ti wọn pe orukọ wọn ni Aṣiru, Fẹmi ati Idris. Ọjọ naa ni wọn bọ sọwọ ikọ Fijilante So-Safe, ti wọn mu wọn ṣinkun lasiko ti wọn n palẹmọ lati tun da wahala silẹ n’Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun.

Ipalẹmọ lati da wahala silẹ naa lo n lọ lọwọ tawọn So-Safe fi gbọ, ti wọn si lọọ ka wọn mọ Opopona Satina, nibi ti wọn fara pamọ si n’Ijẹbu-Ode.

Bi wọn ṣe mu wọn ni wọn ti jẹwọ pe awọn ko niṣẹ meji ju idaluru lọ. Wọn lawọn fẹẹ bẹrẹ omi-in ni ọwọ palaba awọn ṣegi yẹn.

Alukoro So-Safe, Maruf Yusuf, sọ pe awọn ọdọkunrin mẹta naa ṣalaye pe ki wahala ṣẹlẹ ni iṣẹ tawọn mọ ju, nitori ibi tawọn ti n jẹun niyẹn.

Ibọn oriṣii mẹta lawọn fijilante ri gba lọwọ wọn, pẹlu ẹ ni wọn si ko wọn lọ si teṣan ọlọpaa Igbeba, nibi ti wọn yoo ti taari wọn sile-ẹjọ.

Leave a Reply