Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pa ara wọn l’Oṣogbo, mẹwaa lara wọn lọwọ ọlọpaa ti tẹ

Florence Babaṣọla

Ọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Aniyikaye lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti pa laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii lagbegbe Ọwọọpẹ, niluu Oṣogbo.

ALAROYE gbọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun loun naa, ṣugbọn ẹgbẹ tiẹ yatọ si ti awọn ti wọn pa a. Iṣẹlẹ ọhun la gbọ pe o da hilahilo silẹ lagbegbe naa nitori oniruuru awọn nnkan ija lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ko lọọ ka Aniyikaye mọbi ti wọn pa a si.

Ọkan lara awọn to n gbe ni Ọwọọpẹ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiri sọ pe awọn eeyan naa ti ṣiṣẹ ọwọ wọn tan, ti wọn si ti sa lọ ki awọn ọlọpaa too de, ti wọn si fi mọto wọn gbe oku oloogbe naa lọ.

Iṣẹlẹ yii lo fa a ti awọn ọmọ ikọ Amọtẹkun pẹlu agbarijọ awọn agbofinro ti wọn n pe ni JTF fi fọn saarin ilu Oṣogbo, ti wọn si n dọdẹ awọn ọmọ ẹgbẹ kaakiri.

A gbọ pe awọn mẹwaa ni ọwọ ti tẹ bayii, koda, ṣe ni awọn ikọ naa fi ibọn fọ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa to doju ija kọ wọn lẹsẹ, o si n gba itọju lọwọ nileewosan kan.

Gbogbo awọn ibuba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn de, gẹgẹ bi ọkan lara wọn ṣe sọ fawọn oniroyin, wọn si ti pinnu pe iwa-ipa yoo dopin nipinlẹ Ọṣun.

SP Yẹmisi Ọpalọla to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa, ati pe iwadii ti bẹrẹ lati waṣu desalẹ ikoko wahala to ṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply