Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pa eeyan mẹta l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

 

Titi di asiko ti a n koroyin yii jọ, paroparo ni agbegbe Kọlawọle, Orita Alie, ati Ọbalende, niluu Oṣogbo, da latari bi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe ṣọṣẹ nibẹ laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

A gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Aiye ni wọn n ṣoro kaakiri bii agbọn, ti wọn si n dọdẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n jẹ Ẹyẹ kaakiri.

Laago mẹjọ aarọ ni wọn bẹrẹ iṣẹ lorita Alie, lagbegbe Ọbatẹ. Ṣogo Owonikoko, ti inagijẹ rẹ n jẹ Marley ni wọn kọkọ yinbọn pa niwaju ile rẹ nibẹ.

Lẹyin naa ni wọn kọja si agbegbe Kọlawọle, wọn yinbọn pa Daniel to jẹ Ibo lati ori ọkada ti wọn wa lasiko to n lọ sọdọ ọrẹ rẹ kan laduugbo ọhun, ori nibọn ti ba a, loju-ẹsẹ lo jade laye.

 

Bakan naa la gbọ pe wọn ṣa ọmọkunrin kan, Afeez, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Ẹja pa lagbegbe Ọbalende, niluu Oṣogbo.

Ẹnikan to n gbe lagbegbe Kọlawọle so pe awọn ọlọpaa ni wọn waa gbe oku Daniel nibi to ku si, iṣẹlẹ naa si ti da ibẹrubojo sọkan awọn eeyan agbegbe naa nitori wọn ko mọ boya awọn eeyan naa le pada wa tabi bẹẹ kọ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe akọsilẹ eeyan kan ṣoṣo lo wa lọdọ awọn ọlọpaa pe o ku laaarọ ọjọ Aiku yii.

Gẹgẹ bo ṣe wi, obinrin kan, Nafisat Owonikoko, to n gbe ni Ita-Olookan, lo lọọ sọ fawọn ọlọpaa pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye yinbọn pa ọkọ oun, Sogo Owonikoko, toun fura pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ Ẹyẹ, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, lagbegbe Ọbatẹ, laago mẹwaa aarọ.

O ni awọn ọlọpaa ti lọ sibẹ, wọn si ti gbe oku rẹ lọ sile igbokui-pamọ-si ni Ọṣun State Teaching Hospital, Oṣogbo, nigba ti iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply