‘Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ni ki n mu ẹjẹ wa ni mo ṣe yin ọmọ ọga mi lọrun pa’

Faith Adebọla, Eko

Chiamaka Odo, lorukọ ọmọbinrin ọmọọdun mẹrinla yii, oun ni ọga rẹ fi ìkókó, ọmọ oṣu mẹfa pere, ti lagbegbe Gberigbe, n’Ikorodu, lati ba oun mojuto o, ṣugbọn niṣe lo yin ọmọ naa lọrun pa lọjọ kẹfa, oṣu Kẹta yii, ki ọga rẹ too de, o tun fi ọbẹ gun un nikun, o gbe ẹjẹ ọmọ ọhun, o lawọn ẹlẹgbẹ okunkun ni wọn ni koun mu ẹjẹ rẹ wa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Adekunle Ajiṣebutu, lo sọ ọrọ yii di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta yii, nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdaran tọwọ awọn agbofinro ṣẹṣẹ ba l’Ekoo, ni olu-ileeṣẹ wọn to wa n’Ikẹja.

Chiamaka jẹwọ pe awọn olori ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Ogoloma, eyi toun naa jẹ ọmọ ẹgbẹ wọn, ni wọn ni koun mu ẹjẹ ọmọ naa wa loun ṣe pa a. O ni atigba toun ti wa niluu Enugu, nipinlẹ Enugu, loun ti n ṣẹgbẹ okunkun naa.

Nigba t’ALAROYE wadii ọrọ wo lẹnu ẹ, o ni ọdun meji sẹyin loun darapọ mọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun naa, o ni ọrẹ oun kan lo fa oun wọnu ẹgbẹ ọhun, lati le maa gbeja ara oun loun ṣe n ṣe e.

O loun kabaamọ nnkan toun ṣe, oun si bẹ awọn ọlọpaa ati ọga oun lati forijin oun.

Ajiṣebutu ni afurasi ọdaran naa maa foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply