Awọn ọmọ ẹgbẹ PDP binu si Agboọla, Igbakeji Gomina Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo ni wọn fẹhonu han tako magomago ti wọn lo fẹẹ waye ninu eto ibo abẹle ẹgbẹ ọhun to fẹẹ waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ to n bọ. Awọn olufẹhonu han yii ni wọn ya bo olu ile ẹgbẹ naa to wa lagbegbe Fiwaṣaye, Alagbaka, niluu Akurẹ, lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pẹlu ọkan-o-jọkan akọle bii, a ko ni i gba kẹ ẹ ta ẹtọ wa, Secondus gbọdọ bọwọ fun ifẹ awọn ọmọ ẹgbẹ, ẹ ma ṣe da wahala silẹ nipinlẹ Ondo eyi ti wọn gbe lọwọ.

Ọkan ninu awọn tinu n bi ọhun to sọrọ lorukọ awọn yooku, Ọnarebu Bitire Solomon ni iroyin ti tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ lọwọ pe wọn ti ṣafikun awọn ayederu orukọ awọn aṣoju bii ọgọrun-un o le ẹyọ kan (101) si eyi ojulowo eyi to wa nilẹ tẹlẹ.

Alaga ijọba ibilẹ Okitipupa nigba kan ri ọhun ni awọn ko ni i tẹwọ gba iwe akọsilẹ orukọ mi-in ti wọn ba fẹẹ ṣamulo lasiko eto ibo abẹle naa to ba ti le yatọ si eyi to wa nilẹ tẹlẹ. O ni awọn aṣaaju ẹgbẹ PDP lorilẹ-ede yii gbọdọ yọ orukọ Agboọla Ajayi kuro ninu awọn to fẹẹ kopa ninu eto ibo abẹle naa niwọn igba to ti lọwọ ninu ṣiṣẹ magomago si orukọ awọn aṣoju naa. Bakan naa lo tun n beere fun fifi panpẹ ofin gbe Ọgbẹni Kingsley Chinda to jẹ akọwe igbimọ to ṣeto yiyan awọn aṣoju kaakiri awọn wọọdu idibo to wa nipinlẹ Ondo.

Ninu ọrọ tirẹ, Clement Faboyede to jẹ alaga afunsọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ondo ni oun ko mọ ohunkohun lori awọn ẹsun tawọn olufẹhonu han ọhun ka silẹ. O rọ wọn lati kọ gbogbo ohun to n dun wọn sinu iwe ki oun le ba wọn fi sọwọ si awọn asaaju ẹgbẹ l’Abuja.

Ọnarebu Agboọla Ajayi ti wọn fẹsun kan ko jẹ kọrọ tutu toun naa fi fun awọn to n fẹhonu han naa ọhun lesi lori awọn ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ. Igbakeji gomina ọhun ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ akọwe iroyin rẹ, Babatọpẹ Ọkẹowo, ni ohun ti ko bojumu rara ni bi wọn ṣe n darukọ oun lori awọn nnkan ti oun ko mọ nnkan kan nipa rẹ.

O ni gbogbo awọn to n fẹhonu han yẹ ki wọn mọ pe oun ko fi igba kan si lara ọmọ igbimọ ti wọn ṣagbekale lati yan awọn aṣoju lawọn wọodu to wa nipinlẹ Ondo. O ni awọn aṣaaju ẹgbẹ l’Abuja lo yẹ kawọn eeyan ọhun doju ibinu wọn kọ niwọn igba to jẹ pawọn ni wọn yan awọn ọmọ igbimọ to ṣeto naa.

Agboọla ni oun ko ba ẹnikẹni ja, bẹẹ ni ko si ọrọ bo o ba a o pa a, bo o si ba a ko o bu u lẹsẹ ninu ọrọ oṣelu ti oun n ṣe. O rọ awọn alatako rẹ ki wọn yee pariwo lasan, o ni ṣe lo yẹ ki wọn fi awọn aṣoju wọnyi silẹ ki wọn dibo yan oludije ti wọn ba mọ pe o kunju oṣuwọn ti yoo si jawe olubori ninu eto idibo gomina to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Leave a Reply