Awọn ọmọ ẹgbẹ PDP darapọ mọ APC ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ti gbalejo ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn ju ẹgbẹ ọhun silẹ bii amuku ọsan, ti wọn si dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Abdulrasaq gbalejo wọn lati fi sami ayẹyẹ ijọba awa-ara-wa niluu Ilọrin ti ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.

Lara awọn to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ni oludije sipo Aarẹ tẹlẹ ninu ẹgbẹ ACPN, Alhaji Ganiyu Galadimo, ati gbogbo awọn alaga kansu tẹlẹ lawọn ijọba ibilẹ mẹrẹẹrindinlogun ti wọn dibo yan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Alhaji Abdullahi Samari, to sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun sọ pe ẹgbẹ ti tẹwọ gba awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ati ọmọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu miiran to le ni ẹgbẹrun mẹta jake-jado ipinlẹ Kwara, ti wọn si sọ pe, aseyori ti ẹgbẹ APC ẹka ti Kwara ti ṣe labẹ iṣejọba Abdulrahman Abdulrasaq lo wu awọn lórí tawọn fi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu onitẹsiwaju ọhun.

Leave a Reply