Awọn ọmọ ẹgbẹ PDP fẹhonu han l’Ọṣun, wọn ni Oyinlọla ki i ṣe igba ikolẹ idile Adeleke

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wahala ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ọṣun tun gba ibomi-in yọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ Odo-Ọtin fẹhonu han lori bi awọn kan ṣe pariwo le gomina ana, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, lori niluu Oṣogbo laipẹ yii.

Irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee to kọja, ni ALAROYEgbọ pe Oyinlọla, gẹgẹ bii ọkan lara awọn agbaagba ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun, lọ si ileetura Laim, niluu Oṣogbo, lati lọọ ṣepade pẹlu awọn igbimọ ti awọn alakooso apapọ ẹgbẹ ran wa latilu Abuja lati ṣakoso idibo wọọdu.

Ṣugbọn latari bi ile-ẹjọ giga kan niluu Ileefẹ ṣe kede lọjọ naa pe bi wọn ṣe deede yẹ aga mọ Ọnarebu Sọji Adagunodo nidii gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa l’Ọṣun ko bojumu, igbimọ naa kede pe wọn yoo sun idibo wọọdu naa siwaju.

Eyi la gbọ pe o bi awọn kan ti awọn ara Odo-Ọtin nigbagbọ pe wọn jẹ alatilẹyin Sẹnetọ Ademọla Adeleke ninu, ti wọn si bẹrẹ si i ho le Oyinlọla lori bo ṣe debẹ.

Ninu fidio ti ALAROYE ri nipa iṣẹlẹ naa, ṣe lawọn eeyan naa n pariwo ‘ole’, ‘agbaaya’ mọ Oyinlọla lori, bẹẹ ni wọn n pariwo pe ‘Adeleke la fẹ’. Bi ariwo naa ṣe pọ to, ṣe ni Oyinlọla n rẹrin-in muṣẹ bi awọn oṣiṣẹ alaabo ṣe n dọgbọn mu un kuro laarin wọn.

Idi niyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa kaakiri gbogbo wọọdu mẹẹẹdogun to wa nijọba ibilẹ Odo-Ọtin fi fọn sita lọjọ Aiku, pẹlu ewe lọwọ wọn ati oniruuru akọle ti wọn gbe lọwọ.

 

Wọn sọ pe ọkan pataki lara awọn adari ti gbogbo ilu fẹran, ti gbogbo eeyan si mọ pe ki i ri agba fin ni Ọmọọba Oyinlọla, awọn ko si ni i faaye gba awọn idile Adeleke lati sọ ọ di igba iṣanwọ.

Awọn olufẹhonu han ọhun, ti wọn kora jọ siwaju gbọngan ilu Okuku, fi ẹsun kan alaga igun kan ninu ẹgbẹ PDP l’Ọṣun, Ọnarebu Sunday Bisi ati Sẹnetọ Ademọla Adeleke, to wa lara awọn oludije mẹfa ti wọn gba fọọmu gomina, pe awọn ni wọn wa nidii ikọlu naa.

Nigba to n sọrọ, Ọnarebu Lekan Oyediran to jẹ ọkan lara awọn olufẹhonu han ọhun sọ pe iwa abuku gbaa ni wọn hu si Oyinlọla, o ni gbangba lawọn ri i pe idile Adeleke ni wọn wa nidii iṣẹlẹ naa.

Oyediran ni ti ki i baa ṣe ti awọn agbofinro ti wọn tete dide si ọrọ naa nibẹ, Ọlọrun nikan lo mọ iru nnkan ti iba ṣẹlẹ si Oyinlọla lọjọ naa. O ni ko si agbalagba kankan to le sọ pe Oyinlọla ri oun fin ri, nitori olufẹ alaafia ni. Oyediran ke si awọn alakooso apapọ ẹgbẹ naa lati da si wahala yii, o ni Senetọ Ayu ko gbọdọ dawọ le iru iwa to mu ki Secondus fabuku kuro nipo alaga apapọ ẹgbẹ naa.

Bakan naa ni Funmilayọ Adebisi sọ pe adari rere ti gbogbo awọn n pọn le lagbegbe naa ni Oyinlọla, to si ti ran ọpọlọpọ lọwọ, idi niyẹn ti awọn ko fi le gba ki ẹgbin kankan gun un latọwọ awọn idile Adeleke.

Leave a Reply