Adefunkẹ Adebiyi
Pẹlu gbogbo afojuri ti wọn la kọja lakata DSS, to si tun jẹ awọn meji ninu wọn ṣi tun wa lahaamọ ikọ ọtẹlẹmuyẹ yii, awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho mejila ọhun ti pe DSS lẹjọ, wọn ni wọn gbọdọ san owo ẹtọ awọn ti wọn tẹ mọlẹ.
Ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa l’Abuja ni wọn pe ẹjọ ọhun si, alaye ti wọn si ṣe ni pe ki kootu paṣẹ fun DSS, ki wọn san ọgọ́rùn-un kan miliọnu naira (100m) fawọn gẹgẹ bii owo ifiyajẹni ati ìfojú-ẹni gbole lai ṣẹ ti wọn ṣe fawọn.
Yatọ si ti owo yii, awọn ọmọọṣẹ ajijagbara tawọn eeyan mọ si Igboho-Ooṣa naa tun ni awọn fẹ ki ikede waye, pe awọn ko ṣẹ ẹṣẹ kankan labẹ ofin to le mu ki DSS dunkooko m’awọn bii eyi.
Wọn lawọn fẹ ki wọn fi ye gbogbo aye pe ko yẹ ki wọn yẹyẹ awọn bii eyi, ko yẹ ki wọn foju awọn ba kootu, ko si lẹtọọ labẹ ofin lati foju awọn wina iya gbogbo ti DSS fi n jẹ awọn.
Awọn eeyan yii sọ pe bi DSS ṣe ti awọn mọle tayọ wakati mẹrindinlaaadọta ti i ṣe ọjọ meji, ta ko ẹtọ awọn labẹ ofin.
Wọn waa fi kun un pe DSS pe awọn akọroyin le awọn lori, wọn ni ki wọn waa foju awọn han nita gẹgẹ bii ọdaran nigba ti kootu kankan ko ti i pe awọn lọdaran.
Awọn ọmọ ẹyin Igboho ni eyi lodi labẹ ofin, o ba orukọ awọn jẹ, o si ta ko abala ofin Naijiria ti wọn ṣe lọdun 1999, eyi to ni a ko ni i pe ẹnikẹni larufin, afi ti ile-ẹjọ ba ri i pe tọhun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an loootọ.
Ẹjọ yii ti wa niwaju adajọ, ibi ti wọn yoo da a si lawọn eeyan n reti bayii.