Awọn ọmọ iya kan naa mẹta ku somi nibi ti wọn ti n luwẹẹ lodo

Jọkẹ Amọri

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn mọlẹbi ṣi n banujẹ lori iṣẹlẹ ibanujẹ kan to ṣẹlẹ si tọkọ-tiyawo kan ti ẹnikẹni ko ti i mọ orukọ wọn ni adugbo Ajah, nipinlẹ Eko. Ọmọ wọn mẹta, ọmọ ọdun mẹrinla, ọmọ ọdun meje ati mẹta, ti gbogbo wọn jẹ obinrin lo deede ku sinu omi nibi ti wọn ti n wẹ ninu omi iluwẹẹ kan to wa ni inu ẹsiteeti naa niluu Ajah.

Iwe iroyin Punch to fi iroyin naa lede ṣalaye pe obi awọn ọmọ naa jade ni lọjọ kejila, oṣu Kẹfa yii, wọn lọ si ode kan. Lẹyin ti wọn jade lawọn ọmọ wọn mẹtẹẹta ti wọn jẹ obinrin yii jade kuro nile, ti wọn si lọ si ibi odo iluwẹẹ igbalode ti wọn ṣe sinu ẹsiteeti naa, nibi ti ẹnikẹni to ba fẹ ti le wẹ.

Asiko ti awọn ọmọ naa ko sinu odo lati luwẹẹ ni wahala de, ti wọn si ku sinu omi naa lai ri ẹni tete yọ wọn tabi lati doola ẹmi wọn. Iṣẹlẹ naa fi han pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ọmọ yii ko mọ bi wọn ṣe n luwẹẹ, ki wọn kan lo anfaani pe awọn obi wọn ko si nile, ti wọn fi kọri si ibi omi naa, eyi to si pada ṣeku pa awọn ọmọbinrin mẹtẹẹta ti wọn jẹ ọmọ iya ati baba kan naa ti awọn obi wọn n wo loju, wọn ko ni ọmọ mi-in lẹyin awọn ọmọ wọnyi.

A gbọ pe olori ẹṣọ to n ṣo ẹsiteeti naa wa ninu awọn to kọkọ ri oku awọn ọmọ wọnyi to lefoo sori omi. Oju-ẹsẹ ni wọn ti ko wọn lo sọsibitu pẹlu ipinnu lati doola ẹmi wọn, ṣugbọn niṣe ni awọn dokita sọ pe oku ni awọn ọmọ mẹtẹẹta ti wọn ko wa naa.

Wọn pe obi awọn ọmọ yii pe iṣẹlẹ kan to nilo ki wọn fi gbogbo ohun ti wọn n ṣe silẹ, ki wọn si maa bọ kiakia ti ṣẹlẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ fun wọn pe awọn ọmọ wọn ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si. Oju-ẹsẹ ni baba ati iya awọn ọmọ naa ti de, nigba naa ni olori awọn ẹṣọ ẹsiteeti naa ati awọn eeyan mi-in to ti wa nibẹ tufọ iku awọn ọmọ wọn mẹtẹẹta fun wọn. Niṣe ni baba ati iya awọn ọmọ mẹtẹẹta yii daku lọ rangbọndan.

Ọjọ keji iṣẹlẹ naa ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, Awọn eeyan naa fi iṣẹlẹ yii to wọn leti ni agọ olọpaa to wa niluu Ajah.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa waye, o daro pẹlu awọn mọlẹbi naa, bẹẹ lo si bu ẹnu atẹ lu iwa ti awọn eeyan inu ẹsiteeti naa hu pẹlu bi wọn ko ṣe pese awọn nnkan aabo to yẹ ati awọn ohun ti wọn le lo lati maa mojuto awọn to ba n wẹ ninu omi iluwẹẹ naa.

Bakan naa lo gba awọn obi nimọran lati maa mojuto awọn ọmọ wọn. O tun fi kun un pe ki awọn eeyan ma bẹ somi pe awọn fẹẹ wẹ ti ko ba ti si alamoojuto to mọ nipa iwe wiwẹ to le mojuto wọn ti wọn ko fi ni i ri sinu omi. O rọ awọn eeyan ki wọn ma lawọn n lọọ luwẹẹ leti okun ti ko ba si ẹni to maa mojuto wọn nitosi. O kọminu si bi awọn eeyan ṣe n padanu awọn eeyan wọn sinu omi nitori iru idi to ṣee yẹra fun yii.

ALAROYE gbọ pe inu ọfọ gidigidi ni awọn obi awọn ọmọ wọnyi wa. Bẹẹ lo fidi rẹ mulẹ pe wọn ti ko oku awọn ọmọ naa lọ si ile igbokuu-pamọ-si

Leave a Reply