Awọn ọmọ iya meji ti wọn fẹẹ ṣ’oogun owo n’Ijẹbu ti pa iya arugbo o

Ni Ijẹbu Muṣin lo ti ṣẹlẹ. Awọn ọmọ iya kan naa, Akinọla Akeem ati Muyiwa Akeem fẹẹ lowo ni gbogbo ọna, ni wọn ba lọọ ba oniṣegun kan, Moses Ọduntan ti wọn tun n pe ni Koba, pe ko ṣoogun owo fawọn. Niyẹn ba ni ki wọn mu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira wa, oogun owo yoo jẹ ṣiṣe. Owo ti oniṣegun fẹẹ gba ti wọn n wa ni wọn ṣe lọọ digunjale, nibẹ ni wọn ti pa iya agbalagba, Christiana, ẹni ọdun mejilelaaadọrin (72).

Baba arugbo kan ti wọn n pe ni Ọlatokunbọ lo n fọnnu lọdọ awọn ọrẹ rẹ nile ẹmu pe oun ni owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ataabọ Naira (N550,000) nile oun, oun ko si mọ pe ni  gbogbo igba ti oun n tu aṣiri ara oun yii, Muyiwa Akeem to fẹẹ ṣe oogun owo pẹlu ẹgbọn rẹ wa nibẹ to n gbọ. Kia lo lọọ sọ fun ẹgbọn rẹ, ni wọn ba pada sọdọ Koba, oniṣegun wọn. NI iyẹn ba ṣe oogun fun wọn pe ki wọn lọọ fi ji owo naa wa. Lawọn ọmọ baba kan naa yii ba gba ile Baba Ọlatokunbọ lọ. Bi iyawo rẹ ti ri wọn to si ri i pe ole ni wọn lo fẹẹ pariwo, ni Akinọla ba gba a ̀orun mu, t ofọọ di i lẹnu, lo ba wọ ọ wọ inu yara kan, o si yi i lọrun pa. Niya ba ku.

Baba yii ti kọkọ fun wọn ni ẹgbẹrun mẹẹdogun, to ni gbogbo owo to wa lọwo oun niyẹn, ṣugbọn igba to ri i pe wọn fẹẹ pa oun loootọ, o lọọ gbe owo naa jade fun wọn, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ataabọ. Bi wọn ti gba owo naa ni wọn pada wa lati pa baba, oun naa yaa ṣe bi ẹni to ti ku. Wọn ro pe o ti ku ni wọn ṣe fi i silẹ ti wọn lọ. Ni wọn ba gbe owo ti wọn ja gba, o dile Koba. Ni Koba ba fun Akinọla ni ọgọta ẹgbẹrun (N60,000), o fun Muyiwa ni aadọta (N50,000) O ni oun yoo fi eyi to ku ṣe oogun owo fun wọn ni. O ṣe oogun ka fun wọn loootọ, ṣugbọn oogun naa ko ti i di owo lati inu oṣu kẹta ọdun yii ti wọn ti ṣe e, titi ti ọwọ awọn ọlọpaa fi tẹ wọn yii o. Wọn kan pa iya arugbo naa danu lasan ni.

 

Leave a Reply