Monisọla Saka
Gẹgẹ bi Hajj ọdun 2023 ti i ṣe ọkan ninu opo ẹsin Islam tawọn Musulumi maa n ṣe lọdọọdun ṣe n lọ lọwọ, awọn ọmọ Naijiria kan ti padanu ẹmi wọn sọhun-un, bẹẹ lawọn mi-in ti wọn ni ipenija ọpọlọ pọ lọ sua.
Ninu ọrọ ti Usman Galadima ti i ṣe adari awọn ikọ eleto ilera ileeṣẹ to n ri si ọrọ Hajj nilẹ Naijiria, National Hajj Commission of Nigeria, (NAHCON), sọ, o lawọn mẹfa ni wọn ti dagbere faye latigba ti eto naa ti bẹrẹ.
Laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lo sọ eleyii di mimọ lasiko tawọn ajọ naa jokoo ipade niluu Mẹka, lorilẹ-ede Saudi Arabia.
Ipinlẹ mẹta ọtọọtọ lorilẹ-ede Naijiria ni wọn padanu awọn eeyan wọn. Galadima ni eeyan meji meji lo ku ni ipinle Ọṣun ati Kaduna, nigba ti eeyan kan yooku wa lati ipinlẹ Plateau.
O waa ke sawọn ikọ eleto ilera ti wọn maa n ṣe ayẹwo fawọn ti wọn yoo lọ si Mecca, lati tubọ mura si iṣẹ wọn, o ni awọn mi-in wa to jẹ pe ilera wọn ati ipo ti wọn wa ko le gba wọn laaye lati rin iru irinajo bẹẹ. O tẹsiwaju pe o ṣe pataki lati ni eto kan ti yoo maa fofin de awọn ti wọn ko ni i le lanfaani ati lọ, latara esi ayẹwo ti wọn ba ṣe fun wọn.
O ni, “Nnkan ta a n sọ ni pe o yẹ ki wọn tubọ ro ẹka ti wọn ti n ṣayẹwọ ilera fawọn to n lọ Mẹka lagbara. Ko yẹ ko si tabi-ṣugbọn kan nibẹ, ki wọn sọ awọn to le lọ atawọn ti wọn ko ni i le lọ ni. Lara awọn nnkan to ṣe pataki keeyan too gun le iṣẹ Hajj ni ki eeyan ni okun to peye, ko si lowo atawọn nnkan mi-in ti yoo mu ki iṣẹ Hajj rẹ rọrun lọwọ. A n pe fun eto ayẹwo ti wọn n ṣe ki wọn too lọ si Mẹka, eyi to poju owo daadaa si ni pẹlu”.
O ni yatọ sawọn ti wọn ku, awọn eeyan ti wọn n lọ bii ọgbọn mi-in, layẹwo awọn ti fidi ẹ mulẹ pe wọn ni arun ọpọlọ, amọ ti wọn ti n gba itọju lọwọ. O ni pẹlu bi itọju ṣe ti bẹrẹ lori wọn yii, awọn naa yoo ri iṣẹ Hajj wọn ṣe.
“A ti n tọju wọn laaye ta a pese silẹ fawọn tara wọn ko ba ya. Awọn akọṣẹmọṣẹ ti wọn mọ nipa arun ọpọlọ (psychologist), mẹrin ni wọn wa laarin wa. A ti n tọju wọn, o si ṣee ṣe ki gbogbo wọn ri iṣẹ Hajj ṣe nitori ara wọn ti n balẹ bayii”.
Bakan naa lo tun sọ pe ẹni kan bimọ laarin awọn ọmọ Naijiria to waa ṣe Hajj, tawọn meji si padanu oyun wọn.
O ni oyun oṣu meje ni ti ẹni to bimọ, ati pe iṣẹ abẹ ni wọn fi gbẹbi ẹ.
O ni ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn fi ibi egungun rọ, tawọn si tun pada ge ẹsẹ ẹni kan nitori arun itọ ṣuga to n ba a ja.
Galadima waa ke si ileeṣẹ Hajj ilẹ Naijiria, lati ma ṣe mu ọrọ ayẹwo ṣiṣe pẹlu ọwọ yẹpẹrẹ, lati le dena iru awọn iṣẹlẹ bayii, lọjọ iwaju.