Aderounmu Kazeem
Pupọ ninu awọn eeyan orilẹ-ede yii ti wọn gbọ ọrọ ti Aarẹ Muhammed Buhari sọ laṣalẹ oni, Ọjọbọ, Tọsidee ni inu wọn ko dun rara, paapaa bi ko ṣe mẹnuba bi awọn ṣọja ṣe pa awọn ọdọ ni too-geeti Lẹki, l’Ekoo.
Ohun tawọn araalu n sọ bayii ni pe dipo ọrọ ibanikẹdun fawọn eeyan ti wọn padanu ẹbi wọn, atawọn ti wọn padanu dukia olowo iyebiye, ohun ti awọn ọdọ yii bajẹ kiri lo jẹ Aarẹ logun.
Wọn ni ohun ti ijọba ẹ ti ṣe atawọn nnkan to ni lọkan lo kojọ sinu iwe ti wọn kọ fun un, toun naa waa fagbara kaka ka a seti awọn ọmọ Naijiria.
Ni deede aago meje aṣalẹ oni lo gba ori ẹrọ amohunmaworan lọ, nibi to ti ba gbogbo ọmọ Naijira sọrọ. Ninu ọrọ Aarẹ Buhari lo ti sọ pe, ijọba ti gbọ gbogbo ariwo tawọn ọdọ n pa, ati pe igbesẹ to yẹ yoo waye lori ohun gbogbo ti wọn n fẹ.
Buhari ti waa rọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii, paapaa awọn ̀ọdọ ti wọn n ṣewọde kiri wi pe ki wọn kuro lojupopo, ki eto asọyepọ to yẹ le waye lori ohun gbogbo ti wọn sọ pe awọn fẹ.
Siwaju si i, O ni, ko si ohun to n jẹ SARS mọ bayii, bẹẹ loun ko ni i fẹ kawọn eeyan maa wo ijọba bi eyi ti ko ni ohun ṣe pẹlu ohun to n dun wọn lọkan.
Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọdọ kan ṣe kọlu aafin Kabiyesi Akiolu, awọn teṣan ọlọpaa ti wọn kọlu ati ọgba ẹwọn ti wọn kọlu pẹlu. Bẹẹ gẹgẹ lo sọ pe ohun to buru ni bi wọn ti ṣẹ kọlu awọn ileeṣẹ nla nla to jẹ ti ijọba ti wọn ba bajẹ kiri.
Buhari ni ohun to yẹ ki awọn eeyan to n da ilu ri yii lọ mọ ni pe, bi wọn ṣe n beere fun awọn ohun ti yoo ṣe wọn lanfaani, bẹẹ gẹgẹ lo yẹ ki wọn mọ pe ko dara ki wọn tẹ ẹtọ ẹlẹtọ loju mọlẹ pẹlu.