Awọn ọmọ Naijiria fẹẹ gba orileede wọn pada, emi funra mi ni mo maa ṣaaju ipolongo naa-Pasitọ Bakare

Faith Adebọla, Eko

 “Ẹnu mi gbọrọ lati sọ ọ, ko sohun ikọkọ kan ti mo ṣe pamọ si ẹ lọwọ, to ba si wa, bọ si gbangba ko o sọ ọ fun gbogbo aye, o le waa mu mi to o ba to bẹẹ. Mo ti ṣiṣẹ fun ẹ, mo ṣatilẹyin fun ẹ lati de ipo to o wa yẹn, ṣugbọn ti mo ba waa n sọrọ lasiko yii, ẹnu mi ti n run.

Emi o ṣepade pẹlu ẹ mọ, mi o si ṣabẹwo sọdọ ẹ mọ. Lati asiko yii lọ, bo le dogun ko dogun, bo le dija ko dija ni o, dandan ni ki Naijiria dominira.”

Gbajugbaja ajihinrere ati oludasilẹ ṣọọṣi Citadel Global Community Church nni, Pasitọ Tunde Bakare, lo n tu bii ejo bẹẹ lasiko iwaasu rẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii. Ṣugbọn lowe lowe la n lu ilu agidigbo, ọlọgbọn ni i jo o, ọmọran ni i mọ ọn, lo fọrọ ọhun ṣe, pẹlu bi ko ṣe darukọ ẹnikan pato to n fi paṣan ọrọ naa na.

Oludari agba ṣọọṣi Latter Rain to ti pa orukọ da si Citadel Global Community Church, to si tun jẹ ondije fun ipo igbakeji aarẹ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ninu eto idibo ọdun 2011 ọhun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe niṣe nijọba to wa lode yii n fi ẹtẹ silẹ to n pa lapalapa, paapaa latari bi awọn ẹṣọ agbofinro ati ọtẹlẹmuyẹ ijọba apapọ ṣe n sare kiri lori awọn ajijagbara Nnamdi Kanu ati Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti wọn n pe ni Sunday Igboho, bẹẹ si ree, ọrọ awọn janduku afẹmiṣofo ati tawọn Fulani apaayan ati ajinigbe wa nilẹ tijọba o ja a kunra.

O ni ijọba yii ti waa di onikanra, to jẹ gbogbo ẹni to ba ti sọrọ ta ko igbesẹ wọn ni wọn n dọdẹ rẹ kaakiri, ṣugbọn ẹru ko ba oun, oun o si ni i yee sọrọ.

Bakare ni: “Ṣe o ti gbagbe ni, pe o ṣeleri pe o o ni i jade dupo mọ lae, ṣugbọn ti mo sọ fun ẹ pe ma ṣe bẹẹ. Mo fọna han ẹ, mo jẹ ko o mọ bo o ṣe le jawe olubori ninu eto idibo to kan, o si gba pẹlu mi pe waa jade dupo lẹẹkan si i, o si jawe olubori naa. Ki i ṣe tara mi ni mo n ro nigba wọnyẹn, ti Naijiria ni mo n ro.

Ọtọ ni keeyan wọle ibo, ọtọ ni keeyan ṣe nnkan to tọ nipo. Ẹnikan o gbọdọ maa huwa bii pe dukia ẹ ni Naijiria. Naijiria gbọdọ dominira ni, o gbọdọ kuro ninu igbekun yii, gbogbo nnkan idena to ba fẹẹ ṣediwọ la maa yi kuro lọna, dandan ni, Naijiria gbọdọ dalagbara.

Mo kede pe awọn ọmọ Naijiria fẹẹ gba Naijiria pada, emi funra mi ni mo maa ṣaaju ipolongo naa, ipolongo lati sọ Naijiria di ominira.”

Bakare tun ṣeranti pe nigba iṣejọba ologun Sani Abacha, lasiko tijọba naa n gbona janjan, oun sọ asọtẹlẹ pe iṣakoso naa maa dopin lojiji lairotẹlẹ, ẹlomi-in si maa bọ sori aleefa. O lọrọ naa si ṣẹ bẹẹ.

O loun ko fara mọ bijọba to wa lode yii ṣe n sare kiri, to jẹ gbogbo agbara wọn ni wọn n lo lati mu awọn ti wọn ṣe ipolongo idasilẹ orileede mi-in, ti wọn lawọn maa ya kuro lara Naijiria tori ko ṣe wọn loore, bo tilẹ jẹ pe oun o fọwọ si keeyan doju ija kọ ijọba tabi doju ijọba de, ṣugbọn ọtọ nibi to yẹ kijọba dari agbara wọn si.

“Emi o fara mọ iwa ọdaran eyikeyii, mi o si ni i ṣatilẹyin fẹni to fẹẹ doju ijọba de tabi to fẹẹ ba ijọba ja, ko si yẹ kẹnikan maa paayan kiri. Iwa ọdaran niyẹn, wọn si gbọdọ fimu ẹnikẹni to ba ṣeru ẹ danrin.

Sibẹ a gbọdọ mọ pe nnkan to da wahala yii silẹ ni aisi idajọ ododo ati ojooro to n ṣẹlẹ, titi kan eto aabo to mẹhẹ kaakiri. Nibi ti idajọ ododo ba wa, ko le si ojooro, ko si ni i si gbọnmi-si i omi-o-to, ijagbara aa rọlẹ.

Bawo ni wọn ṣe maa maa ṣe sagbasula to to bẹẹ lori ọrọ Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu. Igboho ati Kanu kọ niṣoro Naijiria.

Naijiria gbọdọ ṣe atunto ni, atunto gbọdọ waye ta a ba fẹ ki ariwo ipinya wa sopin ni.”

Leave a Reply

%d bloggers like this: