Awọn ọmọ Naijiria gbe ẹgbẹ okunkun de’luu oyinbo, Italy ni wọn ti mu wọn

Awọn ọlọpaa orilẹ-ede Italy ti mu awọn ọmọ Naijiria mẹẹdogun kan ti wọn n ṣe ẹgbẹ okunkun, awọn ti wọn n pe ara wọn ni ọmọ ẹgbẹ Ẹyẹ.  Naijiria lawọn ọmọ Ẹgbẹ Eyẹ yii ti gbilẹ, ibi ni wọn si fi ṣe olu ile ẹgbẹ imulẹ yii. Ọjọ ti pẹ kanrin-kese ti ẹgbẹ okunkun yii ti wa, paapaa ni awọn ileewe giga ilẹ wa gbogbo. Bi kinni naa ṣe waa deluu oyinbo, to si jẹ awọn ọmọ Naijiria naa ni wọn wa nidii ẹ ni ko ti i ye ẹni kan.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa Polizia ti i ṣe ọlọpaa Italy ti tu wọn jade lọdọ wọn lọhun-un, wọn mu awọn mẹẹdogun, awọn mẹrin mi-in si na papa bora, wọn sa lọ bamu. Ohun ti wọn n fi ẹgbẹ naa ṣe nibẹ ko daa, o si ti pẹ tawọn ọlọpaa yi ti n d’ọdẹ wọn. Wọn ni awọn ni wọn n ko ọpọlọpọ ọmọbinrin Naijiria waa ṣe aṣẹwo ni Italy; awọn ni wọn n fi ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ṣe yahoo yahoo, awọn ni wọn n ran awọn ti wọn n jale lọwọ, ti won s in ran won jade; wọn si mọ bi wọn ti n ko gbogbo owo to ba yọ nidii iṣe okunkun wọnyi pada si Naijiria, tabi ki wọn ba awọn oloṣelu ti wọn ba ji owo ko nile nibi tọju owo wọn soke okun. Nitori ẹ lawọn Polizia yii, ọlọpaa Italo, ṣe n wa wọn lati ọjọ yii wa.

Alẹ ijẹta ni olobó ta wọ́n pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa wa nibi kan ti wọn ti n ṣawo wọn, ẹni to si lọọ ṣofofo wọn ko le ri wọn ti, nitori ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa tẹlẹ ti wọn ṣẹṣẹ fiya jẹ ni. N lawọn ọlọpaa yi ba lọ, nibẹ ni wọn si ti gba wọn mu, ti awọn mẹrin si ribi sa lọ. Ṣugbọn wọn ti ni awọn yoo mu won. Ọgba ẹwọn ti wọn fi awọn eeyan naa si yatọ si ti awọn ọdaran to ku, ibi ti wọn ṣe sọtọ fawọn ọdaran ti wọn gbilẹ kaakiri ọpọ orilẹ-ede ti wọn n pe ni Mafia ni, ẹni ti yoo si bọ nibẹ yoo ṣe ko too jẹ. Awọn ọlọpaa yii ni iwadii nla ti bẹrẹ lori iṣẹ aburu gbogbo ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti ṣe ni Italy, ati ibi ti wọn tun ku si. Bẹẹ bi wọn fẹ, bi wọn kọ, gbogo rẹ ni wọn yoo sọ fawọn.

Leave a Reply