Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ M.A Dada, tile-ẹjọ giga kan niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣẹ owo ilu mọku-mọku ‘Economics And Financial Crime Commission’ (EFCC), wọ awọn ọmọ onilẹ meji kan ti wọn tun n ṣe ejẹnti, Ọgbẹni Majeed Babatunde Rahman, ẹni tawọn eeyan mọ si Mojid Moses Babatunde Rahman, ati ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Oyetubo Jokotade lọ. Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni igbẹjọ wọn tun waye nile-ẹjọ naa.
ALAROYE gbọ pe lati ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2022, ni ẹjọ naa ti wa niwaju adajọ, ṣugbọn fun idi kan tabi omiiran, wọn n sun un siwaju ni nigba gbogbo.
Ẹsun meji ni EFCC fi kan awọn olujẹjọ mejeeji naa. Akọkọ ni pe wọn lu jibiti owo nla laarin ilu. Ẹsun keji ni pe lọdun 2018, wọn ta ilẹ nla kan to jẹ tileeṣẹ ‘C.M.B Building And Maintenance Investment Company Limited’ to wa ni Sango-Tẹdo, lagbegbe Oyemade Royal Family, loju ọna marosẹ Monastery Road, nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko. Miliọnu lọna ẹgbẹrun lọna aadọṣan-an (N165, 000,000M).
Lọọya EFCC bẹnu atẹ lu bawọn olujẹjọ ṣe lọọ ta ile ati dukia awọn ẹni-ẹlẹni lọna ti ko ba ofin mu rara. O ni iwa palapala, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ ni ohun ti wọn ṣe.
Ṣugbọ agbẹjọro awọn olujẹjọ bẹbẹ pe ki adajọ sun igbẹjọ siwaju di asiko mi-in, ki awọn onibaara oun le lanfaani lati wa nile-ẹjọ. Niwọn igba ti awọn olujẹjọ ọhun ko ti si nile-ẹjọ lasiko ti igbẹjọ ọhun n lọ lọwọ, Onidaajọ M.A Dada, sun igbẹjọ siwaju di ọjọ mi-in, o rọ awọn olupẹjọ, iyẹn EFCC, ati olujẹjọ pe ki wọn ri i daju pe gbogbo awọn ẹlẹrii ti wọn ni lati gbe ọrọ wọn lẹsẹ wa nile-ẹjọ lọjọ ti igbẹjọ ba maa waye.