Ọlawale Ajao, Ibadan
Iyawo gomina ipinlẹ Ọyọ, Abilekọ Tamunominini Makinde, ti ṣapejuwe ọyan gẹgẹ bii ounjẹ to daa, to dun, to ṣara loore, to si daa fun gbogbo eeyan lati maa mu.
Amọ ṣaa o, awọn ọmọ ọwọ nikan niyawo gomina yii tọka si gẹgẹ bii ẹni to nilo ounjẹ aṣaraloore naa.
Nibi eto ọlọdọọdun ti wọn fi ṣami ayẹyẹ fifun ọmọ lọyan lo ti sọrọ naa n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.
Nigba to n sọ pataki fifun ọmọ lọyan nikan fun awọn obinrin, Abilekọ Makinde fidi ẹ mulẹ pe ọyan lounjẹ to daa ju ti ikoko gbọdọ mu laijẹ ounjẹ mi-in rara laarin oṣu mẹfa akọkọ ti wọn bi i saye.
Akori ayẹyẹ tọdun yii lo da lori bi awọn oṣiṣẹ ṣe le maa fun ọmọ wọn lọyan daadaa.
O ṣapejuwe omi ọyan gẹgẹ bii omi to mọ, to si jẹ ounjẹ aṣaraloore to daa ju fawọn ọmọ ọwọ.
O waa dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fun bo ṣe n ṣatilẹyin fun awọn obinrin atawọn ọmọde nipinlẹ naa.