Awọn ọmọ ‘Yahoo’ mẹjọ bọ sọwọ awọn EFCC l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ko din lawọn ọmọ Yahoo mẹjọ ti ajọ EFCC, ẹka tipinlẹ Ọyọ, fi pampẹ ofin gbe niluu Akurẹ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Awọn tọwọ tẹ ọhun ni; Ọlasunkami Daramọla, Oluwaṣeyi Akinluyi, Abiọla Mutiu, Adebanjọ Adegoke, Kẹyinde Idowu, Sunday Mọrufu, Adebayọ Ọdẹwumi ati Ridwan Tobilọba.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ile-itura igbalode kan to wa lagbegbe Ọba-Ile, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, ni wọn ka awọn onijibiti ori ẹrọ ayelujara naa mọ ni nnkan bii aago meje alẹ.

Ajọ EFCC ni ọpọlọpọ foonu olowo nla, kọmputa agbeletan atawọn ẹri mi-in to lodi sofin ni wọn ka mọ awọn ọmọ ‘Yahoo’ ọhun lọwọ lati fi ba wọn ṣẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Awọn afurasi ọmọ Yahoo tọwọ tẹ.

Leave a Reply