Awọn ọmọ ‘Yahoo’ yari n’Ileṣa, wọn ni ki EFCC fi awọn lọrun silẹ

Florence Babaṣọla

 

Lọwọlọwọ bayii, inu ibẹrubojo lawọn olugbe ilu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun, wa pẹlu bi awọn ọmọ ‘Yahoo’ ṣe fọn soju popo nidaaji ojo lsegun, Tusidee, ose yii.

A gbọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti lilu jibiti ori ẹrọ ayelujara, EFCC, ko diẹ lara wọn loru-mọjọ, eleyii si bi wọn ninu.

Ariwo ti wọn n pa ni pe wahala awọn EFCC ti pọ ju, wọn ni gbogbo igba ni wọn n mu awọn. Pẹlu igi, okuta, ada ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn n rin kaakiri.

Wọn dana sun taya lawọn ikorita bii Iṣokun Roundabout, Ibala, Oke Omiru ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gbogbo igbiyanju wa lati ba Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọrọ lo ja si pabo nitori ko gbe foonu rẹ lasiko ti a n koroyin yii jọ.

 

Leave a Reply