Awọn ọmọ Yoruba pariwo: Awọn ti wọn fẹẹ ta wa fun Fulani niyi o!

Lọsẹ to koja yii, opọlọpọ awọn ọmọ Yoruba ni wọn binu, wọn si binu gidigidi ni. Lori ẹrọ ayelujara, lori Fesibuuku, itakun Abẹyẹfo (Twitter) ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ko si ibi kan ti wọn ko ti fi ibinu wọn han, paapaa si ọkan pataki ninu awọn aṣaaju Yoruba, Oloye Bisi Akande. Ọpọ awọn ọmọde ni wọn n bu baba naa bii ẹni layin, ọpọ wọn o si fi bo paapaa pe bi awọn ba pade baba ọhun ni gbangba, awọn yoo kọju ija si i. Bi pupọ ninu wọn ṣe n sọ pe awọn ko ni i bọwọ fun un mọ, bẹẹ ni awọn mi-in n sọ pe o ti ba ọmọluabi rẹ jẹ niwaju awọn, ko ni i jẹ ẹni apọnle niwaju awọn mọ titi ti yoo fi ku. Ki lo waa de tawọn yii fi n ṣe bẹẹ, ti wọn si sọ Akande di ọta ọsan-gangan, nigba to jẹ ọkan ninu awọn aṣaaju Yoruba ni wọn ka baba naa si lati ayebaye. Ko si ohun meji to fa a, wọn ni o wa lara awọn to fẹẹ ta wọn fun Fulani ni.

Awọn ti wọn n sọrọ yii ni ẹnikẹni to ba fẹẹ ta Yoruba fun Fulani, ọta awọn ni, o si ti han pe Oloye Bisi Akande wa lara awọn ti wọn gbe iṣẹ naa le lọwọ, nitori bi gbogbo Yoruba ti n pariwo to pe iya n jẹ awọn, baba naa ko sọrọ, ṣugbọn nigba ti ọrọ ba de ibi ko yanju, awọn Fulani ti wọn n ṣejọba yoo lo Akande ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ lati doju ọrọ naa ru pata. Kin ni Akande waa kuku ṣe to bẹẹ lasiko yii? Ohun to ṣẹlẹ ni pe lati bii ọjọ meloo kan ni awọn ọmọ Yoruba kan n ti dide, ti wọn ni iya to n jẹ awọn nilẹ Naijiria yii to gẹẹ, awọn gbọdọ wa nnkan ṣe si i. Ọna meji ni awọn yii pin si, bi awọn kan ti n sọ pe awọn ko gba, ko si ohun to n jẹ Naijiria mọ, awọn yii sọ pe awọn o ṣe mọ, ki Yoruba da duro, ki wọn ni orilẹ-ede tiwọn lo wu awọn, bẹẹ ni awọn apa keji n sọ pe ọrọ naa ko ti i le to bẹẹ, atunto ni ka beere fun, ki wọn tun ofin irẹjẹ to wa ni Naijiria ṣe ni.

Awọn ti wọn ni awọn fẹẹ lọ yii sọ pe bi Yoruba ba ya kuro lara Naijiria, aye awọn ọmọ Yoruba yoo dara gan-an, nitori awọn Hausa ati Fulani ti awọn jọ wa ni wọn n ko ifasẹyin ba wa, wọn lo yẹ ki Yoruba ti kuro ni ipo ti wọn wa ni Naijiria yii, ki awọn naa ti di iran pataki nla kan laarin awọn orilẹ-ede agbaye. Ẹni to ṣe olori awọn yii ni Ọjọgbọn Banji Akintoye ati ẹgbẹ Yoruba World Congress rẹ, ọpọlọpọ awọn ọdọ ti wọn jẹ ọmọ Yoruba kaakiri agbaye ni wọn si wa ninu ẹgbẹ rẹ yii, bẹẹ ni wọn si fara mọ ohun ti wọn n ṣe, pe awọn gbọdọ fi Naijiria silẹ dandan ni. Ṣugbọn awọn apa keji ni ko si ohun to le to bẹẹ, ọrọ to wa nilẹ yii ko ti i le to bẹẹ yẹn, ohun to yẹ ka beere fun naa la n beere fun yii, iyẹn naa ni ki wọn ṣe atunto si ofin Naijiria, nitori ofin Naijiria lo faaye gba awọn Hausa ti wọn fi n rẹ awọn ẹya to ku ni Naijiria jẹ.

Ninu awọn ti wọn n ronu bayii ni awọn agbaagba ẹgbẹ Afẹnifẹre wa, ati awọn ẹgbẹ ajijagbara mi-in. Awọn yii ko nigbagbọ pe awọn yoo kuro ni Naijiria, ṣugbọn ayipada gbọdọ ba ofin ati eto ilẹ yii yikayika. Ninu ilana mejeeji yii, awọn kan wa ṣa ti wọn ko ni igbagbọ ninu eyikeyii ninu ẹ, awọn ọmọ Yoruba ti wọn jẹ aṣaaju ninu ẹgbẹ APC ni. Ninu awọn yii ni Oloye Bọla Ahmed Tinubu ati awọn ti wọn n tẹle e, ninu wọn si ni Oloye Bisi Akande naa wa. Awọn yii ko da si kinni kan, wọn ko fẹ ayipada, wọn ko fẹ ki Yoruba lọ, ohunkohun to ba ṣaa ti le bi awọn Fulani ninu, o da bii pe awọn ko fẹ ẹ. Lọdun to kọja, nigba  tawọn Fulani ajinigbe yinbọn pa ọmọ olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, ti gbogbo eeyan si n lọ sibẹ lati ba baba naa daro, Tinubu lọ sibẹ loootọ, ṣugbọn ko ba baba naa daro, o da kun ibanujẹ fun un ni.

Akọkọ ni pe Tinubu tu awọn aṣiri kan to wa laarin oun ati obinrin to ku naa, o gbe awọn atẹjiṣẹ ti awọn mejeeji jọ n fi ranṣẹ si ara wọn jade, ni eyi to fi han pe Tinubu ti figba kan ran Arabinrin Ọlakunrin yii lọwọ ri. Nigbẹyin lo ni oun fi n ṣalaye ki awọn eeyan le mọ bi oun ati oloogbe naa ti sun mọ ara to ni. Eyi to sọ to buru ju ṣaa ni pe ki i ṣe awọn Fulani lo pa Funkẹ yii, o ni Fulani kọ lo pa a, ko si daa kawọn eeyan maa sọ gbogbo ọrọ iku ati ijinigbe ki wọn maa darukọ Fulani si i. Gbogbo aye pariwo hun-un, ṣugbọn inu awọn eeyan ti wọn jẹ Fulani, ati ara ilẹ Hausa ti wọn n ṣejọba dun si iru ọrọ naa, wọn ni awọn ni onigbeja gidi ninu Tinubu. Ohun ti Tinubu paapaa fẹ ree, o fẹ kawọn eeyan naa ri oun gẹgẹ bii onigbeja, ati ọkan lara awọn to fẹ ti Fulani, ti ko si ni i jẹ ki aburu kan ba wọn nilẹ Yoruba nibi.

Lati igba yii naa lo ti jẹ bi Fulani n paayan l’Oke-Ogun, ti wọn n gbeeyan lọ lọna Ekiti, ko sẹni ti yoo gbọ kinni kan lẹnu awọn Tinubu ati awọn eeyan wọn, bo ba ti jẹ Fulani lọrọ naa kan, wọn yoo dakẹ gbari ni! Nigba tawọn ọlọpaa kede pe awọn ti ri awọn ti wọn pa ọmọbinrin naa nigba ti wọn n lakaka lati ji i gbe, ti wọn si foju wọn han, to jẹ Fulani ni gbogbo wọn. Tinubu ko wi kinni kan mọ, nitori ohun ti wọn fẹẹ lo ọrọ naa fun nigba naa, wọn ti lo o, wọn ti fi gbayi lọdọ awọn Fulani, koda wọn ko fẹ ki iroyin pe wọn ti ri wọn mu yii di ohun ti awọn eeyan tun n gbe kiri mọ. Bi nnkan si ṣe wa niyi ko too di pe eyi to tun ṣẹlẹ yii ṣẹlẹ lọsẹ to kọja.

Nigba ti awọn ọmọ Yoruba n lakaka pe awọn yoo ṣe iwọde ni ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa yii, iyẹn ni Ọjọbọ, Alamisi to kọja yii, awọn eeyan naa gbe Bisi Akande jade, o si ba gbogbo ilakaka wọn jẹ.

Bisi Akande jade nibi ayẹyẹ kan ti ero pe si, ọrọ to si sọ nibẹ ni gbogbo aye n gbe kiri bayii. O ni bi wọn ba fi Yoruba silẹ lati ni orilẹ-ede tiwọn lọtọ, ọgọrun-un ọdun ni awọn Yoruba yoo fi maa ba ara wọn jagun, ogun naa yoo si pada ran kan gbogbo Naijiria, nitori bẹẹ, ki wọn ma ṣe jẹ ki Yoruba da ni orileẹde tiwọn o. Ijọba ti gbọ ọrọ yii, wọn mu un sọwọ, wọn si ko awọn DSS ati ọlọpaa pẹlu ṣọja jade, wọn ko wọn kaakiri ile awọn eeyan ti wọn jẹ aṣaaju Yoruba pata, wọn ni Bisi Akande ti ni wọn ko gbọdọ gba wọn laaye ki wọn ni orilẹ-ede tiwọn. Ohun to bi awọn ọdọ yii ninu ree, ti wọn fi bẹrẹ si i fi eebu ati epe ranṣẹ si i, ati Kunle Ọlajide naa, akọwe ẹgbẹ igbimọ agba toun naa tun sọ iru ọrọ yii, pẹlu Yẹmi Ọṣinbajo to wa ninu ijọba wọn. Wọn ni awọn wọnyi fẹẹ ta awọn fun Fulani, awọn ko si ni i fi ojuure wo wọn laelae.

Leave a Reply