Awọn ọmọbinrin mẹtẹẹta ti Kayọde bi lo ti fipa ba lo pọ n’Ijoko-Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọrọ Baba Ijẹṣa ti wọn lo ba ọmọde lo pọ, ti gbogbo aye n sọ lọwọ ko kọ baba yii, Kayọde Adeniyi, lọgbọn rara, niṣe loun tun ki ọmọ ọdun mẹwaa mọle nile wọn n’Ijoko-Ọta, o si fipa ba a lo pọ karakara laipẹ yii.

Yatọ si ti ọmọ ọdun mẹwaa to ṣe ti aṣiri fi tu yii, awọn ọlọpaa sọ pe Kayọde jẹwọ fawọn pe asiko kan wa to jẹ niṣe loun n ba awọn ọmọ oun obinrin mẹta sun, bo tilẹ jẹ pe ọmọ kekere patapata ni wọn labẹ ofin.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ yii to ALAROYE leti ṣalaye pe obinrin to jẹ ẹgbọn si ọmọ ọdun mẹwaa ti Kayọde ba lo pọ, lo lọọ fejọ sun ni teṣan ọlọpaa Agbado, pe Kayọde, ẹni ọdun mejilelaaadọta (52) to n gbe l’Ojule kejila, Opopona Abẹrẹifa, Ijoko-Ọta, fipa ba aburo oun, ọmọ ọdun mẹwaa, lo pọ.

Obinrin naa ṣalaye pe aburo oun lọ sọdọ awọn Adeniyi lati beere pe ṣe ọmọ rẹ lo ka aṣọ ti oun sa sori okun nita, ṣugbọn baba yii fa a wọle, o fi pilo bo o lẹnu, o si paṣẹ fun un pe ko gbọdọ pariwo titi toun yoo fi ba a ṣe erekere naa tan.

Koda, o loun yoo fi ọbẹ pa a ni bi ko ba fara balẹ koun ba a ṣe. Ohun to jẹ ki ọmọdebinrin naa fara balẹ fun un niyẹn, to si ba a ṣere egele.

Ifisun ẹgbọn ọmọ naa lo jẹ kawọn ọlọpaa lọọ mu Kayọde Adeniyi,  o si jẹwọ fun wọn pe loootọ loun ba ọmọde naa lo pọ, oun si loun yoo fọbẹ pa a loootọ bi ko ba gba.

Nigba ti iwadii tẹsiwaju lawọn ọlọpaa ri i pe awọn ọmọbinrin mẹtẹẹta ti baba yii bi lo ti ba sun tan, oun naa ko si jiyan nigba ti wọn beere lọwọ ẹ, o ni loootọ loun ba awọn ọmọ oun obinrin mẹta lo pọ nigba ti ọjọ ori wọn ko ti i to nnkan kan.

Wọn ti gbe ọmọ ọdun mẹwaa to ṣe kinni fun lọ sọsibitu fun itọju, Ọga ọlọpaa Ogun, Edward Ajogun, si ti ni ki ẹka to n ri si ọrọ mọlẹbi ni Sango maa ba ẹjọ yii lọ.

Leave a Reply