Awọn ọmọde mẹta yii ṣa ọlọkada pa n’Ipẹru, ni wọn ba ji alupupu rẹ lọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Sọdiq Awokọya; ẹni ọdun mejidinlogun(18), Ọdunayọ Samson; ẹni ọdun mejidinlogun ati Jimọh Ridwan; ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17) lẹ n wo yii, ko si eyi ti ọjọ ori rẹ ti i pe ogun ninu wọn. Ṣugbọn bi ẹ ṣe n wo wọn yii, ẹjọ apaniyan ni wọn n lọọ jẹ ni kootu, nitori ọwọ ọlọpaa ti tẹ wọn lẹyin ti wọn ṣa ọlọkada kan, Bashiru Umaru, pa n’Ipẹru-Rẹmọ, ti wọn si gbe ọkada rẹ lọ lati ta a.

Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa yii, ni aṣiri awọn ọmọde naa tu, nigba ti wọn fẹẹ ta ọkada ẹni ti wọn pa naa fẹnikan lagbegbe Toll- Gate, Ogere, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni lasiko tawọn ọmọdekunrin yii fẹẹ ta ọkada naa, ẹni ti wọn fẹẹ ta a fun beere iwe ọkada ọhun ko too le kowo le wọn lọwọ. Nibi ti wọn ti n fesi lori iwe ọkada, ọrọ wọn ko dọgba, alaye ti wọn n ṣe lori ibi ti wọn ti ri maṣinni ọhun ko kun to, n lara ba fun ẹni to fẹẹ ra a, iyẹn si dọgbọn fọrọ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa, bi DPO Abiọdun Ayinde atawọn ikọ rẹ ṣe kọja sibẹ niyẹn ti wọn mu awọn to fẹẹ ta ọkada ọhun.

Nigba ti wọn n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ gan-an, awọn ọmọde yii sọ fawọn ọlọpaa pe awọn ji ọkada naa n’Ipẹru-Rẹmọ ni, eyi lo jẹ kawọn ọlọpaa Ogere fa wọn le ti Ipẹru lọwọ.

Nigba ti Ọlọrun yoo mu wọn, asiko tawọn ọlọpaa gbe wọn de Ipẹru lawọn ẹbi ọlọkada naa waa fẹjọ sun ni teṣan pe awọn ko ri eeyan awọn to fi ọkada ṣiṣẹ lọ mọ. Bẹẹ, pẹlu ọkada tawọn afurasi yii fẹẹ ta lawọn ọlọpaa Ogere de Ipẹru, niṣoju awọn ẹbi ọlọkada ni wọn ṣe gbe e de pẹlu awọn ọmọde yii.

Bawọn ẹbi ọlọkada ṣe ri ọkada ọmọ wọn ni wọn da a mọ, wọ ni ọkada eeyan awọn tawọn n wa ree. Eyi lo mu kawọn ọlọpaa fi kun iwadii wọn lori awọn afurasi yii, lẹyin igba naa ni awọn ọmọde wọnyi ṣẹṣẹ jẹwọ pe awọn ja ọkada naa gba lọwọ ẹni to ni in ni. Wọn ni awọn so ẹni to ni ọkada naa mọgi kan ninu igbo, awọn si gbe ọkada rẹ lọ.

Awọn ọlọpaa ni ki wọn mu awọn lọ sibi ti wọn de ọlọkada naa mọ, kawọn le tu u silẹ, afi bi wọn ṣe debẹ ti wọn ri i pe wọn ti ṣa ọlọkada naa pa ki wọn too gbe alupupu rẹ lọ.

Ninu iwadii awọn ọlọpaa ni wọn ti mọ pe eyi to n jẹ Samson Ọdunayọ ninu awọn ọmọ yii lo pe Bashiru ọlọkada pe ko gbe oun de ibi kan n’Ipẹru, o si ti sọ fun Sọdiq Awokọya pe ko lọọ lugọ de oun nibi kan ninu igbo lagbegbe Ọna Ẹri. Sọdiq to lọọ dena de wọn yii ti mu ada lọwọ atawọn nnkan ija oloro mi-in, ọlọkada nikan ni ko mọ pe wọn ti gbẹ koto iku silẹ foun.

Nigba ti wọn de ibi ti Sọdiq sa pamọ si, Samson sọ fun ọlọkada pe ko duro, oun ti de ibi ti oun n lọ. Biyẹn ṣe duro ni Sọdiq jade lati inu igbo pẹlu ada, o ṣa ọlọkada yanna-yanna. Nibi ti Bashiru ọlọkada ti n japoro iku lọwọ, Samson sun mọ ọn, o yin in lọrun, ọkunrin naa si di oku mọ wọn lọwọ.

Lẹyin iku ọlọkada, wọn tọwọ bọ apo rẹ, wọn si ko ẹgbẹrun marun-un aabọ naira ((5,500), to wa lapo rẹ lọ pẹlu ọkada rẹ.

Aṣe eyi tiẹ kọ ni akọkọ iwa yii tawọn ọmọ naa yoo hu, wọn ti kọkọ da ọlọkada kan lọna, ti wọn gba ẹgbẹrun mẹrin aabọ naira lọwọ iyẹn. Wọn tilẹ fẹẹ pa a bii ti Bashiru yii ni, eyi to n jẹ Jimọh Ridwan ninu wọn lo bẹ awọn meji yooku pe ki wọn ma jẹ kawọn pa a, ki wọn jẹ kawọn fi i silẹ ko maa ba tiẹ lọ.

Ṣugbọn nigba ti wọn fẹẹ lọọ ṣe iṣẹ ti Bashiru ọlọkada yii, wọn ko wulẹ pe Ridwan dani rara, wọn ko fẹ ko maa bẹ awọn pe kawọn ma tun pa a. Nigba ti ko si ti ba wọn lọ, wọn pa a naa ni.

Ada ti wọn fi pa ọlọkada yii ti wa lọdọ awọn ọlọpaa, wọn si ti gba ọkada naa silẹ lọwọ wọn. Kootu lo ku ti awọn mẹtẹẹta yoo lọ laipẹ yii, ti wọn yoo ti ṣalaye ẹnu wọn.

Leave a Reply