Awọn ọmọde yii si pa iya aadọta ọdun, wọn tun yọ ẹya ara ẹ lọ lati fi ṣoogun owo

Iya ẹni aadọta ọdun kan, Abilekọ Patience Komor, ti kagbako iku ojiji, Ọgbẹni Simon Onos, ẹni ogun ọdun pere atọrẹ ẹ, Idogo Akponghene, awọn ni wọn pa iya agbalagba yii, wọn pa a tan ni wọn tun yọbẹ ti i, wọn yọ ẹya ara ẹ lọ, tori wọn fẹẹ ṣoogun owo.

Ba a ṣe gbọ, Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, niṣẹlẹ ibanujẹ naa waye lagbegbe Oleh, nipinlẹ Delta. Ata, tomato atawọn nnkan eelo isebẹ ni wọn ni oloogbe naa n ta, idi ọja rẹ lo si wa ti ọkan lara awọn afurasi ọdaran meji naa, Idogo, fi lọọ ba a, lo ba tan an jade pe agbẹ to n ṣọgbin ata loun, oun si fẹẹ ta ata pupọ fun un, bẹẹ iṣẹ titun bata ṣe gan-an niṣẹ to n ṣe.

Ọgbọn ẹwẹ yii ni wọn loun ati ekeji fi tan mama naa wọgbo, ni wọn ba ko pompo bo iya oniyaa, wọn si lu u pa loju-ẹsẹ, lẹyin naa ni wọn tun yọ obẹ ti oku mama naa, wọn bẹrẹ si i kun un bii ẹni kun maaluu, wọn yọ ẹya ara rẹ kan lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, Ọgbẹni Bright Edafẹ, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe awọn mejeeji ti jẹwọ pe lẹyin tawọn ṣiṣẹ laabi wọn tan lawọn dọgbọn da yeepẹ bo oku oloogbe, ni wọn ba sa lọ.

Agbegbe Kwale ni wọn lọọ fori pamọ si, ṣugbọn olobo pada ta awọn ọlọpaa, wọn tọpasẹ wọn, wọn si ri awọn mejeeji mu.

Edafe ni wọn ti jẹwọ pe loootọ lawọn huwa ọdaju buruku naa, wọn ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira lẹnikan fun awọn pe kawọn fi ba oun wa ẹya ara obinrin toun le lo fun oogun owo.

O lọwọ ko ti i ba ẹni ti wọn lo fẹẹ lo ẹya ara eeyan naa, awọn ṣi n wa babalawo wọn to fẹẹ ba wọn ṣoogun owo, ṣugbọn ni bayii na, akata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lawọn afurasi naa wa. O ni iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn.

Leave a Reply