Awọn ọmọleewe ipinlẹ Ogun yoo wọle pada lọjọ kọkanlelogun oṣu yii o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lẹyin oṣu mẹfa tawọn ileewe ti wa ni titipa nipinlẹ Ogun, ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ti paṣẹ pe ki wọn ṣi awọn sukuu naa pada lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan -an yii.

Akọwe iroyin fun gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita nirọle ọjọ Aje, Mọnde ọjọ keje, oṣu yii.

Kinni kan to waa ṣe pataki ninu ikede yii ni pe ipele-ipele ni iwọle-pada naa yoo jẹ, ki i ṣe pe wọn yoo maa wa papọ ni kilaasi bii ti tẹlẹ. Awọn akẹkọọ pamari lati iwe kin-in-ni si ikẹta yoo maa wa ni kilaasi lati aago mẹjọ aarọ di aago mọkanla aarọ.

Awọn akẹkọọ oniwee kẹrin si ikẹfa yoo maa wa nileewe lati aago mejila ọsan si aago mẹ́ta.Awọn to wa nipele kin-in-ni sikẹta nileewe girama{JSS1 si JSS 3} yoo maa bẹrẹ ikẹkọọ tiwọn laago mẹjọ aarọ, wọn yoo maa jade laago mọkanla aarọ. Awọn to wa nipele agba {SSS 1 si SSS 3} yoo maa lọ sileewe laago mejila, wọn yoo maa pari ẹ laago mẹta ọsan lojoojumọ. Awọn ileewe giga naa le ṣilẹkun wọn lọjọ tijọba la kalẹ yii to ba wu wọn.

Awọn ileewe ẹkọṣẹ ọwọ ko ni ayipada kankan ni tiwọn, aago mẹjọ aarọ si meji ọsan ti wọn n lo tẹlẹ naa ni wọn yoo maa lo lọ. Ṣugbọn awọn ọmọde ti wọn ko ju ọdun mẹta si marun-un lọ nileewe ijọba ko ni i ti i wọle ni tiwọn, o di ipele keji ileewe ṣiṣi bi ijọba Ogun ṣe wi.

Atẹjade naa fi kun un pe gbogbo akẹkọọ n wọle si kilaasi tuntun to yẹ ki wọn bẹrẹ ni saa igbẹkọ 2020 \2021 ni, ko si ọmọ kan ti yoo tun kilaasi ka latari wahala ti Korona da silẹ, ifasẹyin kan ko ni i ba ẹkọ awọn ọmọleewe rara.

Ṣugbọn o, gbogbo ofin to de Korona nijọba paṣẹ pe o gbọdọ wa nipamọ lawọn ileewe yii ki wọn too bẹrẹ ẹkọ pada o. Wọn ni aaye iyasọtọ gbọdọ wa, ọṣẹ ifọwọ atomi pẹlu sanitaisa gbọdọ wa, wọn gbọdọ maa lo ibomu, wọn gbọdọ maa fi aaye itakete silẹ, ko gbọdọ si tito lori ila laraarọ, wọn si gbọdọ maa yẹ ipo ti ara awọn akẹkọọ wa wo pẹlu ẹrọ to wa fun eyi, ẹni ti tiẹ ba gbona ju yoo le tete bọ saaye itọju.

Gbogbo awọn nnkan wonyi tawọn Ileewe ijọba nilo nijọba loun ti ba minisiri eto ẹkọ sọ pe ki wọn pese ẹ, bẹẹ lo rọ awọn aladaani naa pe ki wọn ri i daju pe gbogbo nnkan yii wa lọdọ wón sẹpẹsẹpẹ.

 

Leave a Reply