Awọn ọmoleewe to fẹẹ ṣedanwo yoo wọle lọsẹ to n bọ

Awọn ọmọleewe to fẹẹ ṣedanwo oniwee mẹwaa jade ti jagun ajaye o: ijọba ti fun wọn laaye lati wọle pada sileewe wọn, ki wọn le ṣedanwo naa. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to n bọ, ọjọ Kẹrin oṣu kẹjọ yii ni wọn yoo wọle. Ana ni ijọba apapọ kede bẹẹ, nitori wọn ko fẹ kawọn akẹkọọ ti wọn fẹẹ jade naa kuna lati ṣedanwo wọn.

Tẹlẹtẹlẹ, ijọba ti ni wọn ko ni i jẹ ki awọn ọmọleewe yii wọle nitori arun korona, wọn ni ẹmi awọn ọmo naa ju idanwo ti wọn fẹe ṣe lọ. Ṣgbọn lẹyin ti wọn ti gbe ọrọ naa yẹwo, ti wọn si ti fi ofin ti awọn onileewe gbogbo gbọdọ tẹ le ki wọn too ṣi ileewe wọn lelẹ,  wọn ni awon akẹkọọ yii le lọọ ṣedanwo naa ti yoo bẹrẹ ni ọjo kẹtadinlogun oṣu kẹjọ yii, iyẹn ni wọn si ṣe fun wọn ni ọsẹ meji fun igbaradi, ti wọn ni ki gbogbo ileewe ṣilẹkun wọn.

Leave a Reply