Stephen Ajagbe, Ilọrin
Ko si beeyan ṣe jẹ ọdaju to, ti onitọhun ba ri ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Abdulqudus Bello, tawọn ọmọọta fi ororo gbigbona wẹ, nitori pọfupọọfu, nibi to ti n jẹrora lori ibusun nilewosan yoo kaaanu ẹ.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, lọna Adabata, lagbegbe Agaka, niluu Ilọrin.
Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe nibi ti Abdulqudus ti n din pọfupọọfu ta lawọn ọmọọta adugbo ti waa ba a, ti wọn si ni dandan ko fun awọn ni kinni ọhun jẹ lọfẹẹ.
Wọn ni ọdọmọkunrin naa bẹ wọn lati ṣe suuru diẹ koun fi da awọn onibaara to wa nilẹ lohun. Ṣugbọn ṣe ni inu bi ọkan lara wọn, Alaba, tiyẹn wa lati Baboko, to si fipa gba agbada ororo to wa lori ina, oju ẹsẹ lo fi ororo naa wẹ Qudus lati oju si gbogbo ara rẹ.
Ṣe ni gbogbo oju rẹ bo torotoro, ni wọn ba sare gbe e lọ silewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, nibi to ti n gba itọju.
Baba rẹ, Mallam Idowu Alarape, to n gbe lagbegbe Okekere, niluu Ilorin, rọ ijọba atawọn ti Ọlọrun ṣẹgi ọla fun lati ran an lọwọ lori itọju ọmọ naa.
O ni gbogbo owo tawọn ni lawọn ti na le e lori, nibi tọrọ de duro bayii ati jẹun ti n di iṣoro fawọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ajayi Ọkasanmi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni afurasi ọhun ti wa lahaamọ ọgba ẹwọn ni Mandala.