Awọn ọmọọta kọ lu ọkọ awọn akọroyin to kọwọọrin pẹlu Tinubu

Jọkẹ Amọri
Laarin Ebute Ero si Adeniji, si Iga Iduganran, nibi ti aafin ọba Eko wa ni awọn ọmọọta kan ti kọ lu mọto awọn akọroyin to kọwọọrin pẹlu gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lọjọ Aiku, Sunday, ọṣẹ yii.
ALAROYE gbọ pe lasiko ti ọkunrin oloṣelu naa ṣe abẹwo ‘ẹ kuule’ si ọba Eko nigba to n ti ilu Abuja bọ lẹyin ọjọ diẹ to ti lọ fun ipade abẹle ẹgbẹ wọn to gbe e wọle niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Wọn ni niṣe ni awọn ọmọọta naa n juko nla nla lu ọkọ awọn akọroyin yii, eyi ko si yọ ọkọ awọn alejo pataki pataki to ba Tinubu kọwọọrin lọjọ yii.
Lara wọn ni ọkọ Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje atawọn bẹẹ bẹẹ lọ ni kete ti wọn kuro laafin Ọba Rilwan Akinolu to jẹ Eleko tilu Eko.
Gbogbo gilaasi ọkọ awọn akọroyin naa ni wọn bajẹ, ti okuta ti wọn n ju si ba awọn akọroyin kan, to si ṣe wọn leṣẹ.
Ọpọ awọn akọroyin yii ni wọn fara pa yanna yanna lasiko akọlu naa, awọn mi-in ninu wọn ni lati bẹrẹ sinu mọto naa ki okuta naa ma baa ba wọn, ṣugbọn o pada ba awọn kan ninu wọn, to si ṣe wọn leṣe.
Ko ti i sẹni to mọ pato ohun to n bi awọn ọmọọta yii ninu ti wọn fi hu iru iwa bẹẹ.

Leave a Reply