Awọn oniṣowo igi fẹhonu han l’Akurẹ, wọn ni Akeredolu n febi pa awọn.

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ariwo, ‘ẹ ba wa be Aketi ko si igbo pada, ebi ti fẹẹ pa wa ku mọ inu ile’ lo gba ẹnu awọn oniṣowo igi nipinlẹ Ondo kan lasiko ti wọn n fẹhonu han ta ko bi ijọba Rotimi Akeredolu ṣe ti igbo ọba pa lati bii ọdun diẹ sẹyin.

Alaga ẹgbẹ ọhun, Ẹniọwọ Williams Atibioke, to gba ẹnu awọn yooku sọrọ ni o le lọọọdunrun eeyan ti iṣẹ ti bọ lọwọ wọn, ti wọn ko si ri nnkan kan ṣe mọ lati igba tijọba tí ti igbo.

O ni ọpọlọpọ awọn ọba alaye nipinlẹ Ondo ni awọn ti ran sì Aketi ko le ṣi igbo pada, ṣugbọn ti ko gbọrọ si wọn lẹnu.

Ẹni-ọwọ Atibioke ni ohun ti ko bojumu ni bí Gomina Akeredolu ṣe ti igbo mọ awọn, ti ko si jẹ kawọn ṣiṣẹ oojọ awọn, ṣugbọn to ṣi n gba awọn lagilagi laaye lati maa ba iṣẹ wọn lọ ninu igbo.

 

O ni awọn ti figba kan gbe ọrọ awọn lagilagi naa lọ sile-ẹjọ nipasẹ Arakunrin Rotimi Akeredolu nigba ti ko ti i di gomina.

O ni Aketi gan-an lo gbẹnusọ fawọn ẹgbẹ oniṣowo igi gẹdu n’ile-ẹjọ ti adajọ fi da awọn lare lọdun naa lọhun-un, ti wọn si fofin de awọn lagilagi lati ma ṣe wọ inu igbo ọba mọ.

Ida marundinlọgọrin awọn ọdọ lo ni wọn ko niṣẹ mi-in ti wọn n ṣe ju iṣẹ igi gẹdu lọ, gbogbo awọn wọnyi lo ni atijẹ atimu ti di isoro nla fun latari ofin onikumọ ti Gomina ṣe.

Awọn ọmọ ẹgbẹ lapapọ ni awọn bẹ Gomina ko tete tun ero rẹ pa nipa ṣiṣi igbo ọba to ti pada lẹyẹ-o-ṣọka, nitori pe owo to le ni igba biliọnu Naira lawọn ọmọ ẹgbẹ oun ti padanu latari titi igbo ọba pa.

Nigba to n fesi lori ẹsun ti wọn fi kan gomina, kọmisanna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Donald Ọjọgo, rọ awọn olufẹhonu han naa lati mu suuru diẹ si i fun ijọba

O ni kawọn ọmọ ẹgbẹ naa si fọwọ wọnu nitori pe ìjọba ti n gbe igbesẹ lori awọn nnkan ti wọn beere fun.

 

Leave a Reply