Awọn onifayawọ pa aṣọbode l’Owode-Yewa, lẹru ba n ba awọn araalu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bo tilẹ jẹ pe alẹ ọjọ Satide to kọja yii ni awọn onifayawọ kan pa oṣiṣẹ kọstọọmu kan l’Owode-Yewa, nipinlẹ Ogun, titi dasiko yii lẹru ṣi n ba awọn olugbe agbegbe naa, wọn ni o ṣee ṣe kawọn kọsitọọmu fẹẹ gbẹsan iku ẹni wọn tawọn onifayawọ pa.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an ni pe awọn kọsitọọmu gba apo irẹsi ilẹ okeere to pọ lọwọ awọn onifayawọ naa lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu kẹsan-an yii, ni Owode-Yewa to jẹ ẹnu ibode Naijiria ati ilẹ Olominira Bẹnnẹ.

Bi wọn ti gba awọn irẹsi naa tan ti wọn n lọ ni ọkan ninu awọn mọto ti awọn aṣọbode naa gbe wa dẹnukọlẹ, ọkunrin ti wọn pa yii si jẹ dẹrẹba ọkọ to bajẹ ọhun. Nibi to ti sọkalẹ ninu mọto naa to n tun un ṣe lawọn onifayawọ ti ko ogun de gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ti wọn si kọ lu ọkunrin dẹrẹba aṣọbode naa.

Awọn kan sọ pe ibọn ni wọn yin fun un, bẹẹ lawọn mi-in ni wọn fi nnkan lu u nilana ibilẹ ni, eyi to jẹ bi ko ba ri ẹrọ ẹ, afi ko ku.

Agbẹnusọ awọn kọsitọọmu ni ẹkun naa, Theophilus Duniya, fidi ẹ mulẹ lọjọ Abamẹta, Sannde ọsẹ yii, ninu atẹjade to fi sita, pe awọn onifayawọ kan tori apo irẹsi tawọn gba lọwọ wọn, wọn si pa oṣiṣẹ awọn kan danu. O ni awọn onifayawọ naa gbe awọn nnkan ija oloro oriṣiiriṣii wa, ati awọn oogun abẹnugọngọ, wọn si kọ lu oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ ẹ jẹẹjẹ, wọn pa a.

O fi kun un pe mọṣuari ni dẹreba naa wa bayii, nibi ti wọn tọju oku ẹ si.

Ohun to waa ṣẹlẹ yii lo da ibẹru sawọn eeyan lọkan lagbegbe naa, wọn ni ko ma lọọ jẹ pe awọn aṣọbode yii yoo pada wa, ti wọn yoo maa yinbọn lai woju ẹnikẹni, ti alaiṣẹ yoo si maa nipin-in nibẹ.

Leave a Reply