Awọn ọrẹ meji fẹẹ ṣoogun owo, ni wọn ba lọọ ge ori oku ti wọn ṣẹṣẹ sin n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti wọn ti hu oku ti wọn ṣẹṣẹ sin sitẹ oku, ti wọn si ge ori oku naa lati fi ṣoogun owo, ọwọ palaba awọn ọrẹ meji kan, Abideen Raheem ati Moruf Ganiyu, ti segi.

Ni nnkan bii aago mejila oru mọju ijẹta, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu kejila, ọdun 2021 yii, lọwọ tẹ awọn olubi eeyan naa.

Gẹgẹ bi ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ wọn to wa laduugbo Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, awọn ọlọpaa teṣan Mapo, nigboro Ibadan, lo mu wọn.

O ni Maruf lọwọ awọn agbofinro naa kọkọ tẹ. Lẹyin ti iwadii wọn fidi ẹ mulẹ pe  Maruf paapaa lọwọ ninu iwa ọdaran naa ni wọn lọọ fi panpẹ ọba gbe  Abideen naa.

Adugbo Popoyemọja si Idi-Arẹrẹ, n’Ibadan, ni wọn ti da Maruf duro ni nnkan bii aago mejila oru. Ṣugbọn nigba ti wọn yoo yẹ inu ọra poli baagi dudu to fa lọwọ wo, odidi ori oku eeyan ni wọn ba nibẹ. Bẹẹ, ki i ṣe ori oku eeyan lasan, ori tutu to jọ tẹni to ṣẹṣẹ ku gan-an.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Abideen, ẹni ọdun mejilelogoji (42), to n gbe nile Sheu laduugbo Olomi, ni’badan, sọ pe ni itẹ oku ti wọn n pe ni Abode, lopoopona Akanran, n’Ibadan, loun ti hu oku naa, ti oun si fi ọbẹ ge e lori.

 Maruf sọ ninu ọrọ tiẹ pe,Loootọ ni mo sọ fun ọrẹ mi (Abideen) pe mo nilo ori. O pe mi nigba to ri ori naa, mo si fun un lẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn (25,000) gẹgẹ bii owo iṣẹ ẹ.”

LỌjọruu, Wẹsidee yii, lo ṣee ṣe ki wọn gbe awọn afurasi ọdaran naa lọ si kootu gẹgẹ bi CP Onadeko ṣe fidi ẹ mulẹ.

 

Leave a Reply