Awọn ọta Oluwoo taṣiiri ẹ, wọn lo fẹẹ gbowo lọwọ gomina fun igbeyawo to fẹẹ ṣe

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Bonkẹlẹ ni Oluwoo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, kọ lẹta naa, titi di ba a si ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to mọ ẹni to tu aṣiri lẹta ọhun fawọn oniroyin to fi di ohun to gba gbogbo ori ẹrọ ayelujara, tawọn eeyan si n gba ọrọ naa bii ẹni gba igba ọti.

Awọn ọta ọba nla yii lo tu aṣiri jade pe kabiyesi n bẹbẹ fun owo to to miliọnu lọna ogun Naira lọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun lati fi ṣeto igbeyawo mi-in to fẹẹ ṣe.

Lẹta to kọ sijọba Oyetọla naa lo jẹ ki gbogbo eeyan mọ pe Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti riyawo tuntun mi-in bayii, ọkan ninu awọn ọmọọba ilẹ Hausa si ni.

Iwe ti Oluwo kọ sijọba, eyi to buwọ lu funra ara rẹ naa ka pe: IKEDE IGBEYAWO ATI IBEERE FUN OWO IRANLỌWỌ:

‘‘Pẹlu aṣẹ lati ọdọ Ọba (Dokita) Abdulrosheed Adewale Akanbi, Oluwoo tilẹ Iwo, ni mo fi n sọ fun yin pe Oluwoo ti pinnu lati fẹ ọkan ninu awọn ọmọọba lati Kano Emirate, lati idile Ado Bayero.

‘‘Mo fi asiko yi ran Ọlọla wa gomina leti pe iru igbeyawo ọlọla to ni i ṣe pẹlu idile nla meji bayii ni Naijiria yoo nilo owo nla lati ṣe e, eyi to mu ko ṣe pataki lati beere iranlọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun fun owo ati awọn eto mi-in ti ohun gbogbo yoo fi lọ bo ṣe yẹ.

‘‘Owo ta a ti ṣẹ fun eto igbeyawo naa ti le ni miliọnu lọna ogun.

‘‘Gomina wa, Ọba Akanbi gbẹkẹ le yin fun ifọwọ-si ibeere rẹ yii.’’

Bi lẹta naa ṣe lọ niyi o. Ti awọn eeyan si n beere pe ta lo waa gbe lẹta naa sita to fi di ohun ti gbogbo aye n ri. Bawọn kan ṣe n sọ bayii lawọn mi-in n sọ pe ko sohun to buru ninu ohun ti kabiyesi ṣe, wọn ni awọn ọta ọba alaye yii to fẹẹ ṣebajẹ rẹ lo gbe lẹta naa sita, eyi to yẹ ki ileeṣẹ ijọba wadii lati mọ ẹni to wa nidii iru iwa ibajẹ bẹẹ.

 

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu kejila, ọdun 2019, ni Ọba Akanbi kede pe tirela ti gba aarin oun ati Olori Chanel Chin kọja, to si ni onikaluuku ti n lọ lọtọọtọ.

Latigba naa ni Oluwoo ti wa lai ni olori laafin, ti Chanel si gbe ọmọkunrin kan ṣoṣo ti wọn bi fun ara wọn, Oduduwa, lọ.

Amọ ṣa, ninu lẹta kan ti ọba yii kọ sijọba ipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹjọ oṣu keji ọdun yii lo ti sọ fun gomina pe oun ti n mura lati ṣegbeyawo.

O ni oun ti ri iyawo tuntun ninu idile Ado Bayero nipinlẹ Kano, o si beere fun atilẹyin ijọba lori inawo ayẹyẹ igbeyawo naa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i mu ọjọ inawo, sibẹ, gbogbo aye lo ti n ki kabiesi ku imura, ti wọn si n ṣadura pe eleyii yoo jẹ ọba lọwọ.

 

Leave a Reply