Revolution Now fẹhonu han layaajọ ọjọ Ominira l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

Titi di asiko ta a fi pari iroyin yii lawọn ẹgbẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan ti wọn n jẹ Revolution Now n fẹhonu han wọọrọwọ kaakiri isọri-isọri ilu Oṣogbo.

Pẹlu orin ati patako lọwọ wọn ni wọn n sọ pe omi ominira ti n di omi inira mọ awọn ọmọ orileede yii lọwọ, wọn ni pupọ ninu wahala ti orileede yii n dojukọ, lati ọwọ awọn adari wa lo ti wa.

Ninu ọrọ ẹni to dari wọn, Lijofi Victor, o ṣalaye pe ko si nnkan kan to le mu ori eeyan wu rara pẹlu ayajọ ọdun kọkanlelogọta ti orileede Naijiria n ṣe, nitori gbogbo nnkan lo ti dorikodo.

O sọ siwaju pe lori eto ọrọ-aje, o nira fun ọpọ eeyan lati jẹun ẹẹmẹta lasiko yii, nigba ti ọpọ ti wọn nile lori tẹlẹ ti di alainile mọ latari ọwọngogo nnkan lọja.

Ni ti eto aabo, Lijofi ṣalaye pe dipo kijọba gbaju mọ bi wọn yoo ṣe kapa awọn aṣekupani ti wọn n gbẹmi awọn alaiṣẹ kaakiri, awọn olufẹhonu han lalaafia ni wọn n dẹ pampẹ mu kaakiri.

O ni awọn ikọ alaabo gbogbo ti Naijiria ni mọ awọn ti wọn wa nidii iṣekupani ati igbesunmọ mi to n ṣẹlẹ kaakiri, ṣugbọn ṣe ni wọn n fi ẹtẹ silẹ lati pa lapalapa.

O fi kun ọrọ rẹ pe ohun to bojumu fun awọn adari lasiko yii ni ki wọn kọwe fipo silẹ ti wọn ba mọ pe gbogbo nnkan ko ye awọn mọ, ti wọn ba si mọ pe ko si ohun ti awọn le ṣe lati yanju gbogbo wahala to wa nilẹ yii.

Leave a Reply