Awọn ṣọja lo yinbọn pa aburo mi, bẹẹ lọpọ ẹmi tun sun lasiko iwọde SARS ni Lẹkki – Solomon

Jide Alabi

Bo tilẹ jẹ pé ariwo to kọkọ gbalu ni kete tawọn ṣọja kọ lu awọn ọdọ orilẹ ede yii tí wọn lọọ ṣewọde ta ko SARS ni pé kò sẹni tó kù rara, sibẹ, o fẹẹ jọ pé ojoojumọ lawọn eeyan n jade bayii lati fidi ẹ mulẹ ẹ pe ọpọ ẹmi ló bá ìṣẹlẹ ọhun lọ.

Níwájú igbimọ to n gbọ ẹsun ikọlu ọhun nipinlẹ Eko ni Ọgbẹni Nathaniel Solomon ti sọ pé oku mẹrin loun foju oun ri nilẹẹlẹ nigba toun lọọ gbé òkú aburo oun ti wọn pa sí too-geeti Lẹkki, l’Ekoo, lasiko tawọn ṣọja kọ lu awọn ọdọ to n ṣewọde.

Solomon to sọrọ yii wa lára àwọn ọdọ orilẹ-ede yii bíi mẹẹẹdogun tí wọn waa fẹhonu hàn ni kootu ti wọn ti n gbẹjọ nipa awọn to farapa lọwọ awọn ẹṣọ agbofinro SARS atawọn ẹsun mi-in l’Ekoo.

Pẹlu ibanujẹ lo fi ṣàlàyé ipo to ba àbúrò ẹ lẹyin ti ibọn ṣọja ti pa a.

Bakan naa lo fi kun un pé àwọn mọlẹbi oun ti sìn Abouta Solomon sìluu awọn nijọba ibilẹ Mubi, nipinlẹ Adamawa.

Pẹlu fọto aburo ẹ ninu agbara ẹjẹ to wa ni Solomon fi n hàn awọn igbimọ to n gbọ ẹjọ ọhun, bẹẹ ló sọ pe ko sí ootọ pé ọpọ ẹmi ko ba ìṣẹlẹ ọhun lọ, ati pe awọn ṣọja gan-an ni wọn pa aburo oun danu logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

O ni bi wọn ti yin in nibọn lawọn ọrẹ ẹ ti wọn jọ wà níbẹ ti ke soun, tàwọn sí ṣètò láti gbé òkú Abouta kuro nibi iṣẹlẹ ọhun.
O loun ko tiẹ mọ ìgbà tí aburo oun kuro nile, nitori awọn jọ n gbe ni Lẹkki, lagbegbe Marwa, ni.

Ile igbokuu-si kan to n jẹ St Paul’s Mortuary, ni Oyingbo, l’Ekoo, lo sọ pe awon gbe òkú àbúrò ẹ yii lọ, ki wọn too pada gbe e lọ sílùú ẹ ni Keria, nijọba ibilẹ Mubi, nipinlẹ Adamawa.

Solomon fi kun ọrọ ẹ pe gbogbo awọn eeyan agbegbe Marwa, ni Lẹkki, l’Ekoo ni wọn mọ pe àbúrò òun ba ìṣẹlẹ ọhun lọ, ati pe ṣọja gan-an lo yinbọn pa a nitori to waa ṣewọde ta ko idaamu tawọn ẹṣọ agbofinro SARS n ko ba araalu ni too-geeti Lẹkki, niluu Eko.

Leave a Reply