Awọn SARS lo pa aburo mi-Mosun Filani

Aderohunmu Kazeem

Bi ki i baa ṣe ti iwọde to bẹrẹ laipẹ yii, nibi tawọn ọdọ ti n fẹhonu han lodi si SARS, eeyan ko ni i mọ pe awọn agbofinro naa ti figba kan pa mọlẹbi oṣere ilẹ wa nni, Mosun Filani, lẹkun pẹlu bi wọn ṣe pa aburo rẹ, Ọlatubọsun Oluwatosin Filani nifọna-fọnṣu, ti wọn ran ọmọkunrin naa sọrun lojiji lọdun diẹ sẹyin.

Oṣere yii naa ti bọ sita lati sọ bi awọn SARS, ṣe pa aburo ẹ nipakupa ni nnkan bíi ọdun mẹwaa sẹyin. O ni lọjọ Ẹti, Furaidee, kan ni won pa ọmọ ọhun danu lọdun 2010, bẹẹ, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ni, nigba yẹn lọhun-un.

Aya Oduọla, bawọn eeyan ṣe n pe e bayii sọ pe ọ fẹẹ ma si ile iwosan ijọba toun atawọn ẹbi oun ko wa ọmọkunrin naa de, nigba ti yoo si fi di ọjọ Sannde, lẹyin ọjọ meji tawọn ti n wa a lawọn ba oku ẹ nileewosan kan ni Ijaye, niluu Abẹokuta.

Obinrin onitiata yii sọ pe ọkan lara awọn ọlọpaa Eleweran/Ọbantoko, l’Abeokuta, lo ko gbogbo mọlẹbi awọn sinu ibanujẹ lọdun naa lọhun-un pẹlu bo ṣe pa ọmọkunrin awọn danu.

“Irọlẹ ọjọ Ẹti, Fraidee, ni wọn sọ pe wọn ti pa a, owurọ kutu Sannde, ọjọ Aiku, gan-an la too mọ pe nnkan nla ti ṣe wa ninu ẹbi wa. Titi doni, a o mọ nnkan naa pato ti Ọlatubọsun ṣe ti wọn fi pa a ni kekere. Teṣan ọlọpaa mejeeji ta a lọ, niṣe ni wọn n ṣe wa bii ọdaran, ti wọn si tun le wa jade bii ẹran.

“Lẹyin ọpọ wahala ti mo ti ṣe kaakiri Abẹokuta la ba oku ẹ lọsibitu kan n’Ijaye, ki wọn too jẹ ka ye awọn to wa lọsibitu ọhun wo nkọ, niṣe la tun fowo bọ wọn lọwọ.”

Ninu ọrọ ẹ naa lo tun ti sọ pe ihooho loun ba aburo oun lọjọ naa, to ka ọwọ bọnu, ti apa ibi ti ibọn si ti ba a nikun han ketekete.

“Niṣe ni mo bu sẹkun, ti mo bẹrẹ si ni janra mọlẹ nilẹẹlẹ nibẹ laarin awọn oku yooku ti wọn ko jọ. Mo ke titi, aburo mi ko pada ji saye o, bẹẹ awọn ọlọpaa SARS lo pa a danu l’Abeokuta, ohun to si fa sababi iku ojiji yii, a ko mọ ọn titi doni, ati pe wọn ko tiẹ fẹẹ jẹ ki a ri oku ẹ rara.
“Loni-in, awa ọmọ Naijiria, ti sọ pe o to gẹẹ, ipakupa, ifiyajẹni lọna ti ko tọ ti to lorilẹ-ede yii. Sun re o, Ọlatubọsun Oluwatosin Filani. Ọdun 2010 gan-an lawọn ọlọpaa pa ọ nipakupa.” Mosun, lo kọ ọ bẹẹ sori ẹrọ instagraamu rẹ. nigba to n fi atilẹyin rẹ han sawọn ọdọ to n ṣewọde lodi si SARSayelujara ẹ, Instagram.

Ọpọlọpọ eeyan lo ti n ba oṣere yii kẹdun gidigidi lori iku buruku ti wọn fi pa aburo rẹ.

One thought on “Awọn SARS lo pa aburo mi-Mosun Filani

Leave a Reply