Sifu difẹnsi ti mu Ismail at’ọrẹ ẹ to fọ ṣọọbu pẹlu Jẹlili to ra ẹru ole lọwọ wọn l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Ọṣogbo

Ọwọ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn ọdọkunrin meji; Oyejọla Ismail, to jẹ ọmọ ogun ọdun ati Ridwan Awoyinka, toun jẹ ọmọ ọdun mẹẹẹdogun lori ẹsun ole jija.

Atẹjade ti Alukoro ajọ naa, Daniel Adigun, fi sita ṣalaye pe ọkunrin kan to ni sọọbu lagbegbe Ọja-Ọba, niluu Oṣogbo, lo lọọ fi to awọn agbofinro leti pe awọn ole ti fọ sọọbu oun, wọn si ko ọpọlọpọ ọja lọ.

Bayii ni awọn sifu difẹnsi bẹrẹ iwadii, lasiko naa ni ọwọ tẹ Ismail ati Ridwan, ti wọn si jẹwọ pe loootọ lawọn huwa naa.

Wọn jẹwọ pe aago mẹfa idaji lawọn jalẹkun ṣọọbu naa wọle. Lara awọn nnkan ti wọn ji ko ni maṣinni kan ti wọn fi n wa koto (drilling machine), awọn ẹya-ara jẹnẹretọ, maṣinni ti wọn fi n jo nnkan papọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu iwadii ni awọn afurasi naa ti jẹwọ pe Aderẹmi Jẹlili, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, to n ra aṣaku irin (Scrap Buyer) lawọn ta awọn nnkan tawọn ji fun.

Nigba ti wọn mu Jẹlili, o ni irọ ni wọn n pa pe oun ni wọn ta awọn nnkan ti wọn ji fun, sọkẹẹti ati ṣeeni lasan loun ra lọwọ wọn.

Adigun fi kun ọrọ rẹ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ ̀lati mọ ipa ti ẹnikọọkan awọn afurasi naa ko ninu iṣẹlẹ naa lati le mọ iru ẹsun ti ẹnikọọkan wọn yoo koju nile-ẹjọ.

Amọ sa, Hamzat to ni sọọbu ti sọ pe ohun ti oun fẹ ni ki awọn afurasi naa da awọn ọja ti wọn ji pada tabi ki wọn san miliọnu kan o din mẹwaa naira (#990,000).

Leave a Reply