Awọn sọja mu mẹrin balẹ ninu awọn ajinigbe to da awọn arinrin-ajo lọna l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọrọ bẹyin yọ fawọn ikọ ajinigbe kan lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, pẹlu bawọn sọja ṣe yinbọn pa mẹrin ninu wọn lasiko ti wọn n gbiyanju ati ji awọn arinrin-ajo kan gbe loju ọna marosẹ Ọwọ si Ifọn.

Awọn agbebọn ọhun la gbọ pe wọn ti kọkọ ji awọn eeyan kan gbe pamọ lara awọn arinrin-ajo to ko si wọn lọwọ lọjọ naa.

Ibi ti wọn ti n da ọkọ mi-in duro ki wọn le ri awọn ero inu rẹ ji gbe lawọn ọmọ ologun to n rin kaakiri agbegbe naa ti de ba wọn, ti wọn si fija pẹẹta fun bii wakati kan gbako.

Aarin asiko yii ni wọn mu mẹrin ninu awọn janduku ọhun balẹ, tí wọn si fipa gba awọn ẹni ẹlẹni ti wọn ti ji gbe silẹ lọwọ wọn.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni lati bii ọjọ diẹ sẹyin lawọn sọja ti n wa gbogbo inu aginju to wa lagbegbe naa nitori awọn ajinigbe to n fi ibẹ ṣe ibuba wọn.

 

Leave a Reply