Awọn ti wọn gbẹsẹ le asunwọn owo wọn nitori iwọde SARS lẹtọọ ati gba ile-ẹjọ lọ- Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti gba awọn to ṣe agbatẹru fun iwọde SARS ti wọn ṣe kọja nimọran lati gba ile-ẹjọ lọ lori asunwọn owo wọn ti banki apapọ gbẹsẹ le.

Akeredolu sọrọ yii nigba to n kopa lori eto ori tẹlifisan kan laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Alaga awọn gomina Guusu Iwọ-Oorun orilẹ-ede yii ọhun ni bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ lo fun banki apapọ laṣẹ lori awọn asunwọn ti wọn gbẹsẹ le, sibẹ, gbogbo awọn tọrọ kan naa lẹtọọ labẹ ofin la ti pẹjọ ta ko igbesẹ ọhun.

O ni ọpọ igba ni wọn n gbẹsẹ le asunwọn awọn oloṣelu kan lorilẹ-ede yii, ti ile-ẹjọ si n ba wọn yanju rẹ niwọn igba ti wọn ba ti ṣalaye ọna ti owo naa gba de bẹ ati ohun ti wọn fẹẹ fi ṣe.

Leave a Reply