Awọn ti wọn n faṣọ ṣọja jale n’Ijẹbu-Ifẹ ree o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣe ẹ ranti awọn ayederu ṣọja to wọ aṣọ ologun, ti wọn si n da awọn eeyan lọna nibẹrẹ oṣu yii, lagbegbe Ijẹbu -Ifẹ, nipinlẹ Ogun, eyi tawọn ọlọpaa pa ọkan ninu wọn, ọwọ SARS ti tẹ awọn yooku bayii.

Ikechukwu Alore, Ifeanyi Emmanuel, Chibueze Kingsley, Obiora Micheal, Elias John, Vincent Magnus ati Chigozie Micheal lawọn eeyan naa n jẹ. Olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta, ni wọn ti ṣafihan wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ti kaluku wọn si jẹwọ pe ole jija niṣẹ tawọn n ṣe jẹun, ati pe eyi tawọn fi wọṣọ ṣọja yii lo bu awọn lọwọ, nigba tawọn gbegi dina ninu aṣọ ṣọja laago meji aabọ oru, tawọn n da mọto to ba kọja duro tawọn si n gba tọwọ wọn.

Olori awọn adigunjale yii torukọ n jẹ Obiora Micheal, ẹni tawọn SARS fun nibọn nikun to si n de bandeeji mọnu titi dasiko yii,  sọ pe ọkan ninu awọn lo ṣeto awọn aṣọ ṣọja naa.

O ni mọto kan lawọn da duro lasiko kan  tawọn n ṣọṣẹ lọwọ, awọn le ẹni to wa mọto naa wọgbẹ, inu mọto ọhun lawọn ti ba aṣọ ṣọja rẹpẹtẹ tawọn fi n jale yii, bo tilẹ̀ jẹ pe awọn ọlọpaa sọ pe irọ lọkunrin naa n pa.

Nigba to n sọ idi to fi n jale f’ALAROYE, Elias John ṣọ pe iyawo oun lo bimọ pẹlu iṣẹ abẹ, ni wọn ba ni koun lọọ mu ẹgbẹrun marunlelọgọrin (85,000) wa ki wọn too le yọnda ẹ nileewosan. Owo yii lo ni oun wa de ọdọ Ifeanyi, bo ṣe fọna ole jija han oun niyẹn, latigba naa loun ti n ba wọn lọ soko ole jija, tawọn si jọ n pin’wo.

Obiora to jẹ olori ikọ ole naa ṣalaye pe oun ko niṣẹ gidi lọwọ tẹlẹ naa, o ni baranda ọja loun n ba awọn ọlọja ṣe l’Ekoo, ọdun 2018 loun bẹrẹ ole jija, kọwọ palaba too segi lọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an yii, nibi tawọn ọlọpaa ti pa ọkan ninu awọn to n jẹ Muhammed, ti wọn si yinbọn foun naa nikun, to gbe ọta ibọn sa lọ pẹlu irora.

CP Edward Ajogun sọ ninu ọrọ ẹ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Iṣẹgun naa pe nibi ti iyawo Obiora ti n ba a tọju ọgbẹ inu ẹ nile wọn l’Ajangbadi, lawọn ọlọpaa ti ba a, ti wọn mu un.

Ajogun sọ pe ijamba mọto ni Obiora sọ funyawo ẹ pe òun ni, ko jẹwọ fun un pe oun n jale lọwọ ni wọn ta oun nibọn. Ko si le lọ sọsibitu fun itọju ibọn ki wọn ma baa pe ọlọpaa fun un.

Riri tawọn SARS ri awọn ole nla yii mu dun mọ CP Ajogun ninu pupọ, to bẹẹ to jẹ loju awọn akọroyin lo ti fun wọn ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun -un kan Naira (100,000) fun iṣẹ ti wọn ṣe naa.

O rọ wọn lati mura ṣiṣẹ́ si i, ki wọn le máa ri iwuri bii eyi gba, nitori bi wọn ba fa sẹyin, ibawi ni yoo ba de fun wọn.

Ni tawọn tọwọ ba yii, wọn ṣi n gbatẹgun olooru lọdọ awọn SARS lọwọ.

Leave a Reply