‘‘Awọn ti wọn n gbe posi Arẹgbẹṣọla kiri n kede isinku ara wọn ni’’

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC ni ilẹ Ijeṣa ti bu ẹnu atẹ lu iwọde ti awọn kan lagbegbe Alimọshọ, niluu Eko, ṣe lati ta ko Minisita fun ọrọ abẹle, Rauf Arẹgbẹṣọla, wọn ni igbesẹ ti ko bojumu ni.

Lasiko ti awọn naa n fẹhonu han niluu Ileṣa lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, alaga igun ẹgbẹ oṣelu APC to jẹ ti TOP, Ọgbẹni Lọwọ Adebiyi, sọ pe niwọn igba ti wọn ki i sin Musulumi pẹlu posi, ṣe lawọn ti wọn gbe posi lati pẹgan Arẹgbẹṣọla ṣe isinku ara wọn.

Awọn olufẹhonu han ọhun gbe oriṣiiriṣii akọle lọwọ, lara ohun ti wọn kọ sibẹ ni ‘Akinkanju ni Arẹgbẹṣọla’, ‘Ri Arẹgbẹṣọla ki o jawe olubori ninu ibo’, ‘Awa fara mọ Arẹgbẹṣọla, a si gboṣuba fun un’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn ni ki awọn ti wọn n gbogun ti Arẹgbẹṣọla ni Alimọshọ lọọ ki ọwọ ọmọ wọn bọṣọ, nitori awọn ni ẹnikẹni to ba n ba a ja n doju ija kọ.

Nigba ti oun naa n sọrọ lorukọ awọn olufẹhonu han, alaga ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ileṣa tẹlẹ, Azeez Adeṣiji, sọ pe agbegbe Alimọshọ nira fun ẹgbẹ Onitẹsiwaju lati wọ tẹlẹ ko too di pe Arẹgbẹṣọla debẹ.

O ni ọgbọn oṣelu ti Arẹgbẹṣọla ni lo faaye gba ẹgbẹ naa lagbegbe ọhun, to si fa ọpọlọpọ wọnu ẹgbẹ naa.

Adeṣiji fi kun ọrọ rẹ pe Arẹgbẹṣọla ki i ṣe oloṣelu abẹle, minisita ni, o si ti di ipo to lagbara mu, ko si si ẹnikẹni to ba fagidi ti i kuro ninu ẹgbẹ APC.

‘Ko si Musulumi ododo ti wọn fi posi sin ri. Posi ara wọn ni wọn n gbe kaakiri. Isinku ara wọn ni wọn n ṣe.

“Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ, Alimọshọ ni Arẹgbẹṣọla ti bẹrẹ oṣelu rẹ labẹ Oloogbe Dapọ Sarumi, ibẹ lo si ti ṣalabaapade Tinubu lọdun 1991, latibẹ si ni ibaṣepọ to dan mọnran ti wa laarin wọn.

O ni ofo ọjọkeji ọja ni gbogbo ipolongo ibajẹ ti wọn n ṣe nipa Arẹgbẹṣọla, nitori araba ni baba, ẹni ti a ba laba ni baba.

O waa kilọ pe ibi (evil) kankan ko gbọdọ ṣẹlẹ si Arẹgbẹṣọla, ati pe ti iru ẹ ba ṣẹlẹ, gbogbo aẉọn ti wọn huwa naa yoo foju winna ofin.

Leave a Reply