Faith Adebọla, Eko
“Ṣe gbogbo awọn to ni ṣọọbu nibi lo n ta igbo tabi ọti ni? Nigba tẹ ẹ ni ka kẹru wa laarin ọjọ meje pere, nibo lẹ pese fawọn eeyan to ju ẹgbẹrun meji aabọ lọ lati ko lọ? Ṣe k’ebi lu wa pa ni, tori awọn kan n fagbo. Ika nijọba, iwa ailaaanu ni wọn hu yii, Ọlọrun ri gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii, Ọlọrun maa dajọ.” Abilekọ Rẹmi Adegbajo, ọkan lara awọn tijọba wo ṣọọbu rẹ ni Fagba, lo ṣe bayii sọrọ.
Bakan naa ni Ọgbẹni Tajudeen to ni telọ loun n ṣe ninu kọntena oun nibẹ sọ pe oun ṣi n wa ibomi-in toun maa gbe kọntena naa si lọwọ ni, o ni ko sẹni ti ko mọ bo ṣe nira to lati ri aaye ilẹ l’Ekoo, owo gegere lawọn eeyan to ni ilẹ niwaju ile wọn n bu le e.
Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ ni awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si amojuto ayika atawọn ẹsun akanṣe nipinlẹ Eko ṣi n wo awọn ṣọọbu onipako ati kontena to wa lẹgbẹẹ ọna oju-irin lagbegbe Fagba, nijọba ibilẹ Ifakọ-Ijaye, l’Ekoo. Lati ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ni wọn ti gbe katakata lọ sibẹ, ti iṣẹ si bẹrẹ loju ẹsẹ, nnkan bii ẹgbẹrun meji o din ọọdunrun ile onipako, ṣọọbu ati kọntena ni wọn wo.
Bo-o-lọ o-yago lọrọ da bi katakata naa ṣe bẹrẹ si i run awọn ṣọọbu ati kọntena ti wọn to bẹẹrẹ naa womu womu, ti ko si saaye fẹnikẹni lati ko ẹru tabi palẹ ohun kan mọ. Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn eeyan to n ṣe kara- kata ṣi n ba ọrọ-aje wọn lọ ninu ọpọ awọn ṣọọbu naa nigba tawọn oṣiṣẹ ajọ naa yọ si wọn.
Alaga ikọ amuṣẹya naa, CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, lo ṣaaju nibi iṣẹlẹ naa, nigba tawọn eeyan si rọ lọọ ba pe ko fawọn ni ọjọ meji si i ki wọn fi palẹ ẹru wọn mọ, niṣe lo ṣalaye fun wọn pe gbedeke ọjọ meje nijọba fun wọn lati kuro nibẹ, lẹyin eyi lawọn tun fi aaye ọsẹ mẹta mi-in silẹ fun wọn, tori naa, ko ṣee ṣe lati faaye silẹ mọ.
Ẹgbẹyẹmi ni awọn ṣọọbu naa ti di ibuba fawọn ọmọ ganfe atawọn to n ṣowo ti ko bofin mu lagbegbe ọhun, ti wọn n ta eegbogi oloro bii igbo, kokeeni ati ọti lile. Ati pe iwadii tijọba ṣe fihan pe awọn janduku to ṣọṣẹ lagbegbe Fagba lasiko rogbodiyan iwọde ta ko SARS to kọja ko ṣẹyin awọn to n gbe inu awọn ile onipako ati kọntena ọhun.
O ni oniruuru iwa buruku tawọn olubi ẹda kan n hu lo jẹ inu awọn ṣọọbu ati kọntena naa ni wọn maa n mori mu si ti wọn ba ti ṣetan. Ọpọ awọn to n gba ọna naa kọja ni wọn maa n da lọna lalẹ, ti eyi si ti sọ agbegbe naa di ẹrujẹjẹ fawọn olugbe Fagba lọ si Iju ati Iṣaga. Eyi lo fa a tijọba fi pinnu lati wo awọn sọọbu naa danu, yatọ si pe bi wọn ṣe kọ wọn ko bofin mu, ko si sẹni to fun wọn laṣẹ lati kọ iru nnkan bẹẹ si eteeti oju-irin to jẹ ilẹ ijọba.