Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ti gbogbo ọmọ Naijiria n ṣayẹyẹ ayajọ ọdun kọkanlelaaadọta ti Naijiria gbominira kuro lọwọ awọn oyinbo amunisin, ni awọn tinu n bi ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe ifẹhonuhan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ta ko Bukọla Saraki, fẹsun pe o n jẹ gaba le wọn lori ninu ẹgbẹ.
Gbọnmi-si-i, omi-o-to-o, to n ba ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹka ti ipinlẹ Kwara finra tun gbọna ọtun lọjọ yii pẹlu bi awọn kan tinu n bi ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun ṣe ṣe iwọde ta ko igun adari ile aṣofin agba tẹlẹ, Bukọla Saraki, ti wọn si n pariwo ‘a a fẹ Saraki mọ, a o fẹ ijẹgaba Saraki mọ, niluu Ilọrin. Ko din ni wọọdu mẹtalelaaadọwaa (193), to wa nipinlẹ naa ti wọn ti ṣa ara wọn jọ labẹ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni PDP REDEMPTION GROUP, ti wọn si gbe oniruuru patako pẹlu awọn akọle oriṣiiriṣii lọwọ, wọn ni ṣe ni Saraki n ṣe ẹgbẹ oṣelu ọhun gẹgẹ bii ohun ini rẹ, to si n jẹ gaba lori ẹgbẹ wọn.
Lara awọn ẹsun ti wọn tun fi kan an ni pe lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu PDP ṣeto yiyan awọn oloye ẹgbẹ tuntun jake-jado Naijiria, ti wọn si ṣe tiwọn nipinlẹ Kwara, lẹyin-o-rẹyin ni awọn igun Saraki yan awọn oloye tuntun lọna ọtọ bii ẹni pe oun nikan lo ni ẹgbẹ. Awọn tinu n bi ọhun ti waa ke si awọn agbaagba ẹgbẹ l’Abuja pe ki wọn ma ṣe fontẹ lu eto idibo ti igun Saraki ṣe tori pe awọn ni awọn ṣe tawọn lakooko to tọ, to tun yẹ, tori ti wọn ba gba ti igun Saraki wọle, o le sakoba fun ọjọ iwaju ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara.