Awọn to ṣejọba ṣaaju Buhari lo ko Naijiria soko gbese-Senetọ Adeọla Yayi

Faith Adebọla

Bi orileede Naijiria ṣe n luwẹẹ ninu agbami gbese lọwọ yii, ile aṣofin agba ti sọ pe ọrọ naa ki i ṣe ẹbi Aarẹ Muhammadu Buhari rara, wọn ni awọn iṣakoso to ti wa ṣaaju Buhari ni wọn fa a, awọn ni wọn jẹbi gbese kanmọyan to wa lọrun Naijiria.

Lasiko tawọn aṣofin agba naa n jiroro lori akọsilẹ aba eto iṣuna ati afojusun ọdun meji tawọn aṣofin naa ṣe, eyi to waye nileegbimọ wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lo sọrọ naa.

Olori awọn aṣofin ọhun, Sẹnetọ Ahmed Lawan, lo beere lọwọ Sẹnetọ Solomon Ọlamilekan Adeọla to jẹ alaga igbimọ alabẹ ṣekele lori eto iṣuna owo pe ko sọ ero rẹ lori aroye tawọn ẹlẹgbẹ rẹ n ṣe pe ẹru gbese ati owo yiya yoo ṣakoba fun ọrọ-aje Naijiria ati ọjọ-ọla orileede yii.

Sẹnetọ Adeọla fesi pe ko sọgbọn ki ọrọ ẹyawo yii ma waye, o ni awọn to ṣejọba ṣaaju asiko yii lo fa iṣoro naa, ati pe adiẹ ijọba to wa lode yii n laagun gidi, iyẹ ara rẹ ni ko jẹ kawọn eeyan mọ, o ni ijọba Buhari n sapa lati tun nnkan ṣe ni.

Ọpọ gbese tijọba Aarẹ Muhammadu Buhari n san pada lo jẹ lati asiko iṣejọba ologun lo ti bẹrẹ, titi de ọdun mẹrindinlogun ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi ṣakoso, lasiko awọn Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Umaru Musa Yar’Adua ati Goodluck Jonathan. ‘‘Gbese to wa lọrun wa yii ki i ṣe tijọba to wa lode yii, wọn jogun ẹ ni, gbese ajogunba ni.

Niwọn igba to si jẹ pe iṣakoso ki i duro, o n lọ lati ọwọ ẹni kan si omi-in ni, bẹẹ naa ni gbese wọnyi n ta atare lati ọwọ iṣakoso kan si omi-in titi to fi kan eyi to wa lode yii,” gẹgẹ bi Yayi ṣe sọ.

Ṣaaju eyi lawọn aṣofin kan ti koro oju si bi gbese ṣe n pelemọ si i lọrun Naijiria.

Ṣẹnetọ Gabriel Suswam, ọmọ ẹgbẹ PDP lati ipinlẹ Benue beere pe “igba wo gan-an la fẹẹ jawọ ninu ẹyawo aya-i-ya-tan yii, tori ohun tawọn ọmọ Naijiria n beere niyẹn. Owo ti a fi n san ele ori gbese ti ga to ida mẹtadinlaaadọrin ninu ọgọrun-un, to tumọ si pe lori ọgọrun-un naira ti Naijiria ba pa wọle, naira mẹtadinlaaadọrin la fi n san ele ori gbese.”

Ṣugbọn Sẹnetọ Barau Jibrin, ọmọ ẹgbẹ APC lati ipinlẹ Kano, sọ pe ko sohun to buru ninu awọn ẹyawo wọnyi, o lo ṣe pataki lati yawo ki eto ọrọ-aje le tubọ rugọgọ si i, ki nnkan si le rọgbọ fawọn to fẹẹ ṣowo loriṣiiriṣii nilẹ yii.

Nigbẹyin, olori awọn aṣofin naa, Ahmed Lawan, sọ pe loootọ nijọba n yawo lati le pese awọn nnkan amayedẹrun faraalu, sibẹ, o yẹ kawọn tubọ wo gbogbo alakalẹ to we mọ awọn ẹyawo tijọba fẹẹ ṣe yii, fun aridaju pe gbese naa ko ni i mu orileede yii lomi ju bo ṣe yẹ lọ, kawọn too faṣẹ si i.

Bakan naa lo ni ko daa bawọn aṣofin ṣe kẹrẹ latẹyinwa lori ojuṣe wọn lati ri i pe ohun ti wọn tori ẹ yawo ni wọn n na an le lori, tori ọpọ igba lo maa n jẹ pe niṣe nijọba n fi owo ata ra iyọ, eyi si ti mu ifasẹyin wa lawọn ipinlẹ ati lapapọ.

Leave a Reply